O. Sol 2:8-10
O. Sol 2:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ohùn olufẹ mi! sa wò o, o mbọ̀, o nfò lori awọn òke, o mbẹ lori awọn òke kékeké. Olufẹ mi dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin: sa wò o, o duro lẹhin ogiri wa, o yọju loju ferese, o nfi ara rẹ̀ hàn loju ferese ọlọnà. Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.
O. Sol 2:8-10 Yoruba Bible (YCE)
Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀, ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá, ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké. Olólùfẹ́ mi dàbí egbin, tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Ó dúró lẹ́yìn ògiri ilé wa, ó ń yọjú lójú fèrèsé, ó ń yọjú níbi fèrèsé kékeré tí ó wà lókè. Olùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó wí fún mi pé, “Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi, jẹ́ kí á máa lọ.”
O. Sol 2:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀. Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèkéé Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé, “Dìde, Olólùfẹ́ mi, arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.