O. Sol 2:7-17

O. Sol 2:7-17 Yoruba Bible (YCE)

Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ní orúkọ egbin, ati ti àgbọ̀nrín pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí ìfẹ́ títí yóo fi wù ú láti jí. Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀, ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá, ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké. Olólùfẹ́ mi dàbí egbin, tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Ó dúró lẹ́yìn ògiri ilé wa, ó ń yọjú lójú fèrèsé, ó ń yọjú níbi fèrèsé kékeré tí ó wà lókè. Olùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó wí fún mi pé, “Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi, jẹ́ kí á máa lọ.” Àkókò òtútù ti lọ, òjò sì ti dáwọ́ dúró. Àwọn òdòdó ti hù jáde, àkókò orin kíkọ ti tó, a sì ti ń gbọ́ ohùn àwọn àdàbà ní ilẹ̀ wa. Àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń so èso, àjàrà tí ń tanná, ìtànná wọn sì ń tú òórùn dídùn jáde. Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi, jẹ́ kí á máa lọ. Àdàbà mi, tí ó wà ninu pàlàpálá òkúta, ní ibi kọ́lọ́fín òkúta, jẹ́ kí n rójú rẹ, kí n gbọ́ ohùn rẹ, nítorí ohùn rẹ dùn, ojú rẹ sì dára. Mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ wọ̀n-ọn-nì, àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí wọn ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, nítorí ọgbà àjàrà wa tí ń tanná. Olùfẹ́ mi ni ó ni mí, èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi, ó ń da àwọn ẹran rẹ̀, wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì. Tún pada wá! Olùfẹ́ mi, títí ilẹ̀ yóo fi mọ́, tí òjìji kò ní sí mọ́. Pada wá bí egbin ati akọ àgbọ̀nrín, lórí àwọn òkè págunpàgun.

O. Sol 2:7-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú. Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀. Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèkéé Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé, “Dìde, Olólùfẹ́ mi, arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi. Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá; òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ. Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀ àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa. Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde, àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn, Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi; Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.” Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta, ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga, fi ojú rẹ hàn mí, jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ; Nítorí tí ohùn rẹ dùn, tí ojú rẹ sì ní ẹwà. Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèkéé tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná. Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀; Ó ń jẹ láàrín àwọn koríko lílì. Títí ìgbà ìtura ọjọ́ títí òjìji yóò fi fò lọ, yípadà, olùfẹ́ mi, kí o sì dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín lórí òkè Beteri.