O. Sol 2:4-16
O. Sol 2:4-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
O mu mi wá si ile ọti-waini, Ifẹ si ni ọpagun rẹ̀ lori mi. Fi akara didùn da mi duro, fi eso igi tù mi ni inu: nitori aisàn ifẹ nṣe mi. Ọwọ osì rẹ̀ mbẹ labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ si gbá mi mọra. Mo fi awọn abo egbin, ati awọn abo agbọnrin igbẹ fi nyin bú, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u. Ohùn olufẹ mi! sa wò o, o mbọ̀, o nfò lori awọn òke, o mbẹ lori awọn òke kékeké. Olufẹ mi dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin: sa wò o, o duro lẹhin ogiri wa, o yọju loju ferese, o nfi ara rẹ̀ hàn loju ferese ọlọnà. Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ. Sa wò o, ìgba otutu ti kọja, òjo ti da, o si ti lọ. Awọn itanna eweko farahàn lori ilẹ; akoko ikọrin awọn ẹiyẹ de, a si gbọ ohùn àdaba ni ilẹ wa. Igi ọ̀pọtọ so eso titun, awọn àjara funni ni õrun daradara nipa itanná wọn. Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ. Adaba mi, ti o wà ninu pàlapala okuta, ni ibi ìkọkọ okuta, jẹ ki emi ri oju rẹ, jẹ ki emi gbọ́ ohùn rẹ; nitori didùn ni ohùn rẹ, oju rẹ si li ẹwà. Mu awọn kọ̀lọkọlọ fun wa, awọn kọ̀lọkọlọ kékeké ti mba àjara jẹ: nitori àjara wa ni itanná. Olufẹ mi ni temi, emi si ni tirẹ̀: o njẹ lãrin awọn lili.
O. Sol 2:4-16 Yoruba Bible (YCE)
Ó mú mi wá sí ilé àsè ńlá, ìfẹ́ ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi. Fún mi ni èso àjàrà gbígbẹ jẹ, kí ara mi mókun, fún mi ní èso ápù jẹ kí ara tù mí, nítorí pé, àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. Ó wù mí kí ọwọ́ òsì rẹ̀ wà ní ìgbèrí mi, kí ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fà mí mọ́ra. Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ní orúkọ egbin, ati ti àgbọ̀nrín pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí ìfẹ́ títí yóo fi wù ú láti jí. Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀, ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá, ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké. Olólùfẹ́ mi dàbí egbin, tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Ó dúró lẹ́yìn ògiri ilé wa, ó ń yọjú lójú fèrèsé, ó ń yọjú níbi fèrèsé kékeré tí ó wà lókè. Olùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó wí fún mi pé, “Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi, jẹ́ kí á máa lọ.” Àkókò òtútù ti lọ, òjò sì ti dáwọ́ dúró. Àwọn òdòdó ti hù jáde, àkókò orin kíkọ ti tó, a sì ti ń gbọ́ ohùn àwọn àdàbà ní ilẹ̀ wa. Àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń so èso, àjàrà tí ń tanná, ìtànná wọn sì ń tú òórùn dídùn jáde. Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi, jẹ́ kí á máa lọ. Àdàbà mi, tí ó wà ninu pàlàpálá òkúta, ní ibi kọ́lọ́fín òkúta, jẹ́ kí n rójú rẹ, kí n gbọ́ ohùn rẹ, nítorí ohùn rẹ dùn, ojú rẹ sì dára. Mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ wọ̀n-ọn-nì, àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí wọn ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, nítorí ọgbà àjàrà wa tí ń tanná. Olùfẹ́ mi ni ó ni mí, èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi, ó ń da àwọn ẹran rẹ̀, wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì.
O. Sol 2:4-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àsè, ìfẹ́ sì ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi. Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró. Fi èso ápù tù mi lára nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú. Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀. Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèkéé Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé, “Dìde, Olólùfẹ́ mi, arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi. Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá; òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ. Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀ àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa. Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde, àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn, Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi; Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.” Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta, ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga, fi ojú rẹ hàn mí, jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ; Nítorí tí ohùn rẹ dùn, tí ojú rẹ sì ní ẹwà. Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèkéé tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná. Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀; Ó ń jẹ láàrín àwọn koríko lílì.