O. Sol 2:2-8
O. Sol 2:2-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi itanná lili lãrin ẹgún, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọbinrin. Bi igi eleso lãrin awọn igi igbẹ, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọkunrin. Emi fi ayọ̀ nla joko labẹ ojiji rẹ̀, eso rẹ̀ si dùn mọ mi li ẹnu. O mu mi wá si ile ọti-waini, Ifẹ si ni ọpagun rẹ̀ lori mi. Fi akara didùn da mi duro, fi eso igi tù mi ni inu: nitori aisàn ifẹ nṣe mi. Ọwọ osì rẹ̀ mbẹ labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ si gbá mi mọra. Mo fi awọn abo egbin, ati awọn abo agbọnrin igbẹ fi nyin bú, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u. Ohùn olufẹ mi! sa wò o, o mbọ̀, o nfò lori awọn òke, o mbẹ lori awọn òke kékeké.
O. Sol 2:2-8 Yoruba Bible (YCE)
Bí òdòdó lílì ti rí láàrin ẹ̀gún, ni olólùfẹ́ mi rí láàrin àwọn ọmọge. Bí igi ápù ti rí láàrin àwọn igi igbó, ni olùfẹ́ mí rí láàrin àwọn ọmọkunrin. Pẹlu ìdùnnú ńlá ni mo fi jókòó lábẹ́ òjìji rẹ̀, èso rẹ̀ sì dùn lẹ́nu mi. Ó mú mi wá sí ilé àsè ńlá, ìfẹ́ ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi. Fún mi ni èso àjàrà gbígbẹ jẹ, kí ara mi mókun, fún mi ní èso ápù jẹ kí ara tù mí, nítorí pé, àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. Ó wù mí kí ọwọ́ òsì rẹ̀ wà ní ìgbèrí mi, kí ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fà mí mọ́ra. Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ní orúkọ egbin, ati ti àgbọ̀nrín pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí ìfẹ́ títí yóo fi wù ú láti jí. Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀, ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá, ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.
O. Sol 2:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Bí ìtànná lílì ní àárín ẹ̀gún ni olólùfẹ́ mi ní àárín àwọn wúńdíá. Bí igi ápù láàrín àwọn igi inú igbó, ni olólùfẹ́ mí láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin. Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀, èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu. Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àsè, ìfẹ́ sì ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi. Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró. Fi èso ápù tù mi lára nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú. Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀. Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.