O. Sol 2:10-12
O. Sol 2:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ. Sa wò o, ìgba otutu ti kọja, òjo ti da, o si ti lọ. Awọn itanna eweko farahàn lori ilẹ; akoko ikọrin awọn ẹiyẹ de, a si gbọ ohùn àdaba ni ilẹ wa.
Pín
Kà O. Sol 2O. Sol 2:10-12 Yoruba Bible (YCE)
Olùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó wí fún mi pé, “Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi, jẹ́ kí á máa lọ.” Àkókò òtútù ti lọ, òjò sì ti dáwọ́ dúró. Àwọn òdòdó ti hù jáde, àkókò orin kíkọ ti tó, a sì ti ń gbọ́ ohùn àwọn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
Pín
Kà O. Sol 2O. Sol 2:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé, “Dìde, Olólùfẹ́ mi, arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi. Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá; òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ. Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀ àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
Pín
Kà O. Sol 2