O. Sol 2:1-4
O. Sol 2:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI ni itanná eweko Ṣaroni, ati itanná lili awọn afonifoji. Bi itanná lili lãrin ẹgún, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọbinrin. Bi igi eleso lãrin awọn igi igbẹ, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọkunrin. Emi fi ayọ̀ nla joko labẹ ojiji rẹ̀, eso rẹ̀ si dùn mọ mi li ẹnu. O mu mi wá si ile ọti-waini, Ifẹ si ni ọpagun rẹ̀ lori mi.
O. Sol 2:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Òdòdó Ṣaroni ni mí, ati òdòdó Lílì tí ó wà ninu àfonífojì. Bí òdòdó lílì ti rí láàrin ẹ̀gún, ni olólùfẹ́ mi rí láàrin àwọn ọmọge. Bí igi ápù ti rí láàrin àwọn igi igbó, ni olùfẹ́ mí rí láàrin àwọn ọmọkunrin. Pẹlu ìdùnnú ńlá ni mo fi jókòó lábẹ́ òjìji rẹ̀, èso rẹ̀ sì dùn lẹ́nu mi. Ó mú mi wá sí ilé àsè ńlá, ìfẹ́ ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.
O. Sol 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ni ìtànná Ṣaroni bí ìtànná lílì àwọn Àfonífojì. Bí ìtànná lílì ní àárín ẹ̀gún ni olólùfẹ́ mi ní àárín àwọn wúńdíá. Bí igi ápù láàrín àwọn igi inú igbó, ni olólùfẹ́ mí láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀, Èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu. Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àsè, ìfẹ́ sì ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.