O. Sol 1:7-8
O. Sol 1:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wi fun mi, Iwọ ẹniti ọkàn mi fẹ, nibiti iwọ nṣọ agutan; nibiti iwọ nmu agbo-ẹran rẹ simi li ọsan; ki emi ki o má ba dabi alãrẹ̀ ti o ṣina kiri pẹlu agbo-ẹran awọn ẹgbẹ́ rẹ. Bi iwọ kò ba mọ̀, Iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin, jade lọ ni ipasẹ agbo-ẹran, ki iwọ ki o si bọ́ awọn ọmọ ewurẹ rẹ lẹba agọ awọn aluṣọ-agutan.
O. Sol 1:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́: níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko? Níbo ni wọ́n ti ń sinmi, nígbà tí oòrùn bá mú? Kí n má baà máa wá ọ kiri, láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ? Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin, bí o kò bá mọ ibẹ̀, ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran. Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹko lẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan.
O. Sol 1:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́, níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ. Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán, kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Bí ìwọ kò bá mọ̀, ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin. Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ, kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ. Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn.