O. Sol 1:5-6
O. Sol 1:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi dú, ṣugbọn mo li ẹwà, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi awọn agọ Kedari, bi awọn aṣọ-tita Solomoni. Máṣe wò mi, nitori pe mo dú, nitori pe õrùn ti bojuwò mi: awọn ọmọ iyá mi binu si mi; nwọn fi mi ṣe oluṣọ ọgba-ajara; ṣugbọn ọgba-ajara temi li emi kò tọju.
O. Sol 1:5-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà, mo dàbí àgọ́ Kedari, mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni. Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú, oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀. Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi, wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà, ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára.
O. Sol 1:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi dúdú mo sì ní ẹwà. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu dúdú bí àgọ́ Kedari, bí aṣọ títa ti Solomoni Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú, nítorí oòrùn mú mi dúdú, ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà; ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú.