O. Sol 1:1-17

O. Sol 1:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

ORIN awọn orin ti iṣe ti Solomoni. Jẹ ki o fi ifẹnukonu ẹnu rẹ̀ kò mi li ẹnu nitori ifẹ rẹ sàn jù ọti-waini lọ. Nitoriti õrun ikunra rere rẹ, orukọ rẹ dabi ikunra ti a tú jade, nitorina ni awọn wundia ṣe fẹ ọ. Fà mi, awa o sare tọ̀ ọ: ọba ti mu mi wá sinu iyẹwù rẹ̀: awa o yọ̀, inu wa o si dùn si ọ, awa o ranti ifẹ rẹ jù ọti-waini lọ: nwọn fẹ ọ nitõtọ. Emi dú, ṣugbọn mo li ẹwà, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi awọn agọ Kedari, bi awọn aṣọ-tita Solomoni. Máṣe wò mi, nitori pe mo dú, nitori pe õrùn ti bojuwò mi: awọn ọmọ iyá mi binu si mi; nwọn fi mi ṣe oluṣọ ọgba-ajara; ṣugbọn ọgba-ajara temi li emi kò tọju. Wi fun mi, Iwọ ẹniti ọkàn mi fẹ, nibiti iwọ nṣọ agutan; nibiti iwọ nmu agbo-ẹran rẹ simi li ọsan; ki emi ki o má ba dabi alãrẹ̀ ti o ṣina kiri pẹlu agbo-ẹran awọn ẹgbẹ́ rẹ. Bi iwọ kò ba mọ̀, Iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin, jade lọ ni ipasẹ agbo-ẹran, ki iwọ ki o si bọ́ awọn ọmọ ewurẹ rẹ lẹba agọ awọn aluṣọ-agutan. Olufẹ mi, mo ti fi ọ we ẹṣin mi ninu kẹkẹ́ Farao. Ẹrẹkẹ́ rẹ li ẹwà ninu ọwọ́ ohun ọṣọ́, ọrùn rẹ ninu ilẹkẹ. Awa o ṣe ọwọ́ ohun ọṣọ́ wura fun ọ, pẹlu ami fadaka. Nigbati ọba wà ni ibujoko ijẹun rẹ̀, ororo mi rán õrun rẹ̀ jade. Idi ojia ni olufẹ ọ̀wọ́n mi si mi; on o ma gbe ãrin ọmu mi. Olufẹ mi ri si mi bi ìdi ìtànná igi kipressi ni ọgba-ajara Engedi. Wò o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi; wò o, iwọ li ẹwà: iwọ li oju àdaba. Wò o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi, nitõtọ, o wuni: ibusun wa pẹlu ni itura. Igi kedari ni iti-igi ile wa, igi firi si ni ẹkẹ́ wa.

O. Sol 1:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn orin tí ó dùn jùlọ tí Solomoni kọ nìwọ̀nyí: Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ. Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn, orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde; nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ. Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá, ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀. Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹ a óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ; abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ! Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà, mo dàbí àgọ́ Kedari, mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni. Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú, oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀. Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi, wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà, ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára. Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́: níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko? Níbo ni wọ́n ti ń sinmi, nígbà tí oòrùn bá mú? Kí n má baà máa wá ọ kiri, láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ? Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin, bí o kò bá mọ ibẹ̀, ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran. Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹko lẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan. Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé akọ ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun Farao. Nǹkan ọ̀ṣọ́ mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà, ẹ̀gbà ọrùn sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà. A óo ṣe àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà, tí a fi fadaka ṣe ọnà sí lára fún ọ. Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀, turari mi ń tú òórùn dídùn jáde. Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá, bí ó ti sùn lé mi láyà. Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi, ninu ọgbà àjàrà Engedi. Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi; o lẹ́wà pupọ. Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà. Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi, o lẹ́wà gan-an ni. Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa. Igi Kedari ni òpó ilé wa, igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa.

O. Sol 1:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Orin àwọn orin tí í ṣe orin Solomoni. Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ. Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra. Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ. Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀. Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ; a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ. Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́! Èmi dúdú mo sì ní ẹwà. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu dúdú bí àgọ́ Kedari, bí aṣọ títa ti Solomoni Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú, nítorí oòrùn mú mi dúdú, ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà; ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú. Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́, níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ. Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán, kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Bí ìwọ kò bá mọ̀, ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin. Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ, kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ. Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn. Olùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Farao. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́, ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀ A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ, a ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀. Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀, òróró ìkunra mi tú òórùn jáde. Ìdì òjìá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi, òun ó sinmi lé àárín ọmú mi. Bí ìdì ìtànná Henina ni olùfẹ́ mi rí sí mi láti inú ọgbà àjàrà ti En-Gedi. Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi! Háà, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó! Ìwọ ní ojú ẹyẹlé. Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi! Háà, Báwo ni o ṣe wu ni! Ibùsùn wa ní ìtura. Ìtànṣán ilé wa jẹ́ ti igi kedari ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi firi.