Rut 3:6-7
Rut 3:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà na, o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iya-ọkọ rẹ̀ palaṣẹ fun u. Nigbati Boasi si jẹ ti o si mu tán, ti inu rẹ̀ si dùn, o lọ dubulẹ ni ikangun ikójọ ọkà: on si wá jẹjẹ, o si ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dubulẹ.
Pín
Kà Rut 3Rut 3:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Rutu bá lọ sí ibi ìpakà, ó ṣe bí ìyá ọkọ rẹ̀ ti sọ fún un. Nígbà tí Boasi jẹ, tí ó mu tán, tí inú rẹ̀ sì dùn, ó lọ sùn lẹ́yìn òkítì ọkà Baali tí wọ́n ti pa. Rutu bá rọra lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sùn tì í.
Pín
Kà Rut 3Rut 3:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni Rutu lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un, pé kí o ṣe. Nígbà tí Boasi parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà tí wọ́n kójọ. Rutu yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.
Pín
Kà Rut 3