Rut 3:10-18

Rut 3:10-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

On si wipe, Alabukun ni iwọ lati ọdọ OLUWA wá, ọmọbinrin mi: nitoriti iwọ ṣe ore ikẹhin yi jù ti iṣaju lọ, niwọnbi iwọ kò ti tẹle awọn ọmọkunrin lẹhin, iba ṣe talakà tabi ọlọrọ̀. Njẹ nisisiyi, ọmọbinrin mi máṣe bẹ̀ru; gbogbo eyiti iwọ wi li emi o ṣe fun ọ: nitori gbogbo agbajọ awọn enia mi li o mọ̀ pe obinrin rere ni iwọ iṣe. Njẹ nisisiyi ibatan ti o sunmọ nyin li emi iṣe nitõtọ: ṣugbọn ibatan kan wà ti o sunmọ nyin jù mi lọ. Duro li oru yi, yio si ṣe li owurọ̀, bi on o ba ṣe iṣe ibatan si ọ, gẹgẹ; jẹ ki o ṣe iṣe ibatan: ṣugbọn bi kò ba fẹ́ ṣe iṣe ibatan si ọ, nigbana ni emi o ṣe iṣe ibatan si ọ, bi OLUWA ti wà: dubulẹ titi di owurọ̀. On si dubulẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀ titi di owurọ̀: o si dide ki ẹnikan ki o to mọ̀ ẹnikeji. On si wipe, Má ṣe jẹ ki a mọ̀ pe obinrin kan wá si ilẹ-ipakà. O si wipe, Mú aṣọ-ileke ti mbẹ lara rẹ wá, ki o si dì i mú: nigbati o si dì i mú, o wọ̀n òṣuwọn ọkà-barle mẹfa, o si gbé e rù u: on si wọ̀ ilu lọ. Nigbati o si dé ọdọ iya-ọkọ rẹ̀, on wipe, Iwọ tani nì ọmọbinrin mi? O si wi gbogbo eyiti ọkunrin na ṣe fun on fun u. O si wipe, Òṣuwọn ọkà-barle mẹfa wọnyi li o fi fun mi; nitori o wi fun mi pe, Máṣe ṣanwọ tọ̀ iya-ọkọ rẹ lọ. Nigbana li on wipe, Joko jẹ, ọmọbinrin mi, titi iwọ o fi mọ̀ bi ọ̀ran na yio ti jasi: nitoripe ọkunrin na ki yio simi, titi yio fi pari ọ̀ran na li oni.

Rut 3:10-18 Yoruba Bible (YCE)

Boasi bá dáhùn, ó ní, “OLUWA yóo bukun fún ọ, ọmọ mi, oore tí o ṣe ní ìkẹyìn yìí tóbi ju ti àkọ́kọ́ lọ; nítorí pé o kò wá àwọn ọdọmọkunrin lọ, kì báà jẹ́ olówó tabi talaka. Má bẹ̀rù, ọmọ mi, gbogbo ohun tí o bèèrè ni n óo ṣe fún ọ, nítorí pé gbogbo àwọn ọkunrin ẹlẹgbẹ́ mi ní ilẹ̀ yìí ni wọ́n mọ̀ pé obinrin gidi ni ọ́. Òtítọ́ ni mo jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ rẹ, ṣugbọn ẹnìkan wà tí ó tún súnmọ́ ọn jù mí lọ. Sùn títí di òwúrọ̀, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ bí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn láti ṣú ọ lópó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ rẹ̀, ó dára, jẹ́ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbátan, bí OLUWA ti wà láàyè, n óo ṣe ẹ̀tọ́, gẹ́gẹ́ bí ìbátan tí ó súnmọ́ ọn. Sùn títí di òwúrọ̀.” Rutu bá sùn lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ṣugbọn ó tètè dìde ní àfẹ̀mọ́jú, kí eniyan tó lè dá eniyan mọ̀. Boasi bá kìlọ̀ fún un pé, “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ pé o wá sí ibi ìpakà.” Boasi sọ fún un pe kí ó tẹ́ aṣọ ìlékè rẹ̀, kí ó sì fi ọwọ́ mú un, Rutu náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Boasi wọn ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa sinu aṣọ náà, ó dì í, ó gbé e ru Rutu, Rutu sì pada sí ilé. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ìyá ọkọ rẹ̀ bi í pé, “Báwo ni ibẹ̀ ti rí, ọmọ mi?” Rutu bá sọ gbogbo ohun tí ọkunrin náà ṣe fún un. Ó ní, “Ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa ni ó dì fún mi, nítorí ó sọ pé n kò gbọdọ̀ pada sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ mi ní ọwọ́ òfo.” Naomi bá dáhùn, ó ní, “Fara balẹ̀ ọmọ mi, títí tí o óo fi gbọ́ bí ọ̀rọ̀ náà yóo ti yọrí sí; nítorí pé ara ọkunrin yìí kò ní balẹ̀ títí tí yóo fi yanjú ọ̀rọ̀ náà lónìí.”

Rut 3:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Boasi sì wí fún un pé, “Kí OLúWA bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fihàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù. Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́n ní obìnrin oníwà rere. Nítòótọ́ ni mo wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó súnmọ́ ọ ju ti tèmi lọ. Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí OLúWA ti ń bẹ láààyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.” Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n ó dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ẹnìkínní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Boasi sì sọ fún un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mí mọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀ ìpakà.” Ó sì tún wí fún un pé, “Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀.” Rutu sì ṣe bẹ́ẹ̀, Boasi sì wọn òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú. Nígbà náà ni ó padà sí ìlú. Nígbà tí Rutu dé ilé Naomi ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, “Báwo ni ó ti rí ọmọbìnrin mi?” Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún un fún ìyá ọkọ rẹ̀. Ó fi kún un wí pé, “Ó sọ fún mi wí pé, ‘Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà, ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà barle mẹ́fà.’ ” Naomi sì wí fún un pé, “Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí, nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí.”