Rut 2:8-13
Rut 2:8-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Boasi wi fun Rutu pe, Iwọ kò gbọ́, ọmọbinrin mi? Máṣe lọ peṣẹ́-ọkà li oko miran, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe re ihin kọja, ṣugbọn ki o faramọ́ awọn ọmọbinrin mi nihin. Jẹ ki oju rẹ ki o wà ninu oko ti nwọn nkore rẹ̀, ki iwọ ki o si ma tẹle wọn: emi kò ha ti kìlọ fun awọn ọmọkunrin ki nwọn ki o máṣe tọ́ ọ? ati nigbati ongbẹ ba ngbẹ ọ, lọ si ibi àmu, ki o si mu ninu eyiti awọn ọmọkunrin ti pọn. Nigbana ni o wolẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba silẹ, o si wi fun u pe, Eṣe ti mo ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ o fi kiyesi mi, bẹ̃ni alejo li emi? Boasi si da a lohùn o si wi fun u pe, Gbogbo ohun ti iwọ ṣe fun iya-ọkọ rẹ lati ìgba ikú ọkọ rẹ, li a ti rò fun mi patapata: ati bi iwọ ti fi baba ati iya rẹ, ati ilẹ ibi rẹ silẹ, ti o si wá sọdọ awọn enia ti iwọ kò mọ̀ rí. Ki OLUWA ki o san ẹsan iṣẹ rẹ, ẹsan kikún ni ki a san fun ọ lati ọwọ́ OLUWA Ọlọrun Israeli wá, labẹ apa-iyẹ́ ẹniti iwọ wá gbẹkẹle. Nigbana li o wipe, OLUWA mi, jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ; iwọ sá tù mi ninu, iwọ sá si ti sọ̀rọ rere fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, bi o tilẹ ṣe pe emi kò ri bi ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ rẹ obinrin.
Rut 2:8-13 Yoruba Bible (YCE)
Boasi bá pe Rutu, ó ní, “Gbọ́, ọmọ mi, má lọ sí oko ẹlòmíràn láti ṣa ọkà, má kúrò ní oko yìí, ṣugbọn faramọ́ àwọn ọmọbinrin mi. Oko tí wọn ń kórè rẹ̀ yìí ni kí o kọjú sí, kí o sì máa tẹ̀lé wọn. Mo ti kìlọ̀ fún àwọn ọdọmọkunrin wọnyi pé wọn kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. Nígbà tí òùgnbẹ bá ń gbẹ ọ́, lọ sí ìdí àmù, kí o sì mu ninu omi tí àwọn ọdọmọkunrin wọnyi bá pọn.” Rutu bá wólẹ̀ ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Mo dúpẹ́ pé mo rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ tó báyìí, o sì ṣe akiyesi mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlejò ni mí.” Ṣugbọn Boasi dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ìyá ọkọ rẹ, láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú ni wọ́n ti sọ fún mi patapata, ati bí o ti fi baba ati ìyá rẹ sílẹ̀, tí o kúrò ní ìlú yín, tí o wá sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan tí o kò mọ̀ rí. OLUWA yóo san ẹ̀san gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ọ. Abẹ́ ìyẹ́ apá OLUWA Ọlọrun Israẹli ni o wá, fún ààbò, yóo sì fún ọ ní èrè kíkún.” Rutu bá dáhùn, ó ní, “O ṣàánú mi gan-an ni, oluwa mi, nítorí pé o ti tù mí ninu, o sì ti fi sùúrù bá èmi iranṣẹbinrin rẹ sọ̀rọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin rẹ.”
Rut 2:8-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Boasi sọ fún Rutu pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣá ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi. Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkúgbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.” Rutu wólẹ̀, ó sì wí fún Boasi pé, “Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsi mi, èmi àjèjì àti àlejò?” Boasi sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàrín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Kí OLúWA kí ó san ẹ̀san ohun tí ìwọ ṣe fún ọ. Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ OLúWA Ọlọ́run Israẹli, abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò.” Rutu sì fèsì wí pé, “Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ síwájú sí i olúwa mi. Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.”