Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Rut 2:2YBCV(Bibeli Mimọ)
Rutu ara Moabu si wi fun Naomi pe, Jẹ ki emi lọ si oko nisisiyi, ki emi si ma peṣẹ́-ọkà lẹhin ẹniti emi o ri õre-ọfẹ́ li oju rẹ̀. On si wipe, Lọ, ọmọbinrin mi.
Pín
Rut 2YBCVRut 2:2BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Rutu ará Moabu sì wí fún Naomi pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojúrere rẹ̀ pàdé.” Naomi sì sọ fún un pé, “Máa lọ, ọmọbìnrin mi.”
Pín
Rut 2BMYORut 2:2YCE(Yoruba Bible)
Ní ọjọ́ kan, Rutu sọ fún Naomi, ó ní, “Jẹ́ kí n lọ sí oko ẹnìkan, tí OLUWA bá jẹ́ kí n bá ojurere rẹ̀ pàdé, n ó máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọ́n ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀.” Naomi bá dá a lóhùn, ó ní, “Ó dára, máa lọ, ọmọ mi.”
Pín
Rut 2YCE