Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Rut 2:19YBCV(Bibeli Mimọ)
Iya-ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo ni iwọ gbé peṣẹ́ li oni? nibo ni iwọ si ṣiṣẹ? ibukún ni fun ẹniti o fiyesi ọ. O si sọ ọdọ ẹniti on ṣiṣẹ fun iya-ọkọ rẹ̀, o si wipe, Boasi li orukọ ọkunrin ti mo ṣiṣẹ lọdọ rẹ̀ li oni.
Pín
Rut 2YBCVRut 2:19BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í léèrè wí pé, “Níbo ni ìwọ ti ṣá ọkà lónìí? Àti wí pé oko ta ni ìwọ gbé ṣiṣẹ́? Alábùkún fún ni ọkùnrin náà tí ó bojú wò ọ.” Rutu sì sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé, “Ní oko ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi ni mo ti ṣiṣẹ́ lónìí.”
Pín
Rut 2BMYORut 2:19YCE(Yoruba Bible)
Ìyá ọkọ rẹ̀ bi í léèrè, ó ní, “Níbo ni o ti ṣa ọkà lónìí, níbo ni o sì ti ṣiṣẹ́? OLUWA yóo bukun ẹni tí ó ṣàkíyèsí rẹ.” Rutu bá sọ inú oko ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀, ó ní, “Inú oko ọkunrin kan tí wọ́n ń pè ní Boasi ni mo ti ṣa ọkà lónìí.”
Pín
Rut 2YCE