Rom 9:1-9
Rom 9:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
OTITỌ li emi nsọ ninu Kristi, emi kò ṣeke, ọkàn mi si njẹ mi li ẹrí ninu Ẹmí Mimọ́, Pe mo ni ibinujẹ pupọ, ati ikãnu igbagbogbo li ọkàn mi. Nitori mo fẹrẹ le gbadura pe ki a ké emi tikarami kuro lọdọ Kristi, nitori awọn ará mi, awọn ibatan mi nipa ti ara: Awọn ẹniti iṣe Israeli; ti awọn ẹniti isọdọmọ iṣe, ati ogo, ati majẹmu, ati ifunnilofin, ati ìsin Ọlọrun, ati awọn ileri; Ti ẹniti awọn baba iṣe, ati lati ọdọ awọn ẹniti Kristi ti wá nipa ti ara, ẹniti o bori ohun gbogbo, Ọlọrun olubukún lailai. Amin. Ṣugbọn kì iṣe pe nitori ọrọ Ọlọrun di asan. Kì sá iṣe gbogbo awọn ti o ti inu Israeli wá, awọn ni Israeli: Bẹ̃ni kì iṣe pe, nitori nwọn jẹ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn li ọmọ: ṣugbọn, ninu Isaaki li a ó ti pè irú-ọmọ rẹ. Eyini ni pe, ki iṣe awọn ọmọ nipa ti ara, ni ọmọ Ọlọrun: ṣugbọn awọn ọmọ ileri li a kà ni irú-ọmọ. Nitori ọ̀rọ ileri li eyi, Niwoyi amọdun li emi ó wá; Sara yio si ni ọmọkunrin.
Rom 9:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Òtítọ́ ni ohun tí mò ń sọ yìí; n kò purọ́, nítorí Kristi ni ó ni mí. Ọkàn mi tí Ẹ̀mí ń darí sì jẹ́ mi lẹ́rìí pẹlu, pé, ohun ìbànújẹ́ ńlá ati ẹ̀dùn ọkàn ni ọ̀ràn àwọn eniyan mi jẹ́ fún mi nígbà gbogbo. Mo fẹ́rẹ̀ lè gbadura pé kí á sọ èmi fúnra mi di ẹni ègún, kí á yà mí nípa kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí ti àwọn ará mi, àwọn tí a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà. Ọmọ Israẹli ni wọ́n. Àwọn ni Ọlọrun yàn bí ọmọ rẹ̀. Àwọn ni ó fi ògo rẹ̀ hàn fún. Àwọn náà ni ó bá dá majẹmu, tí ó fún ní Òfin rẹ̀, tí ó sì kọ́ lọ́nà ẹ̀sìn rẹ̀. Àwọn ni ó ṣe ìlérí fún. Àwọn ni irú-ọmọ àwọn baba-ńlá ayé àtijọ́. Láàrin wọn ni Mesaya sì ti wá sáyé gẹ́gẹ́ bí eniyan. Ìyìn ni fún Ọlọrun, ẹni tíí ṣe olùdarí ohun gbogbo, lae ati laelae. Amin. Sibẹ, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kùnà patapata. Nítorí kì í ṣe gbogbo àwọn tí a bí sinu ìdílé Israẹli ni ọmọ Israẹli tòótọ́. Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ìran Abrahamu ni ọmọ rẹ̀ tòótọ́, nítorí bí Ìwé Mímọ́ ti wí, Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Àwọn ọmọ Isaaki nìkan ni a óo kà sí ìran fún ọ.” Èyí ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ tí a bí nípa ti ara lásán ni ọmọ Ọlọrun. Àwọn ọmọ tí a bí nípa ìlérí Ọlọrun ni a kà sí ìran Abrahamu. Nítorí báyìí ni ọ̀rọ̀ ìlérí náà: “Nígbà tí mo bá pada wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóo ti bí ọmọkunrin kan.”
Rom 9:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú Kristi, èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́. Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi. Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara. Àwọn ẹni tí i ṣe Israẹli; tí àwọn ẹni tí ìsọdọmọ í ṣe, àti ògo, àti májẹ̀mú, àti ìfúnilófin, àti ìsìn Ọlọ́run, àti àwọn ìlérí. Tí ẹni tí àwọn Baba í ṣe, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí Kristi ti wá nípa ti ara, ẹni tí ó borí ohun gbogbo, Ọlọ́run olùbùkún láéláé. Àmín. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli: Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ: Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.” Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”