Rom 8:11-16
Rom 8:11-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi Ẹmí ẹniti o jí Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu okú yio fi Ẹmí rẹ̀ ti ngbe inu nyin, sọ ara kikú nyin di ãye pẹlu. Njẹ nitorina, ara, ajigbèsè li awa, ki iṣe ara li a jẹ ni gbese, ti a o fi mã wà nipa ti ara. Nitori bi ẹnyin ba wà ni ti ara, ẹnyin ó kú: ṣugbọn nipa Ẹmí bi ẹnyin ba npa iṣẹ́ ti ara run, ẹnyin ó yè. Nitori iye awọn ti a nṣe amọ̀na fun lati ọdọ Ẹmí Ọlọrun wá, awọn ni iṣe ọmọ Ọlọrun. Nitori ẹnyin kò tun gbà ẹmí ẹrú lati mã bẹ̀ru mọ́: ṣugbọn ẹnyin ti gbà ẹmí isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi nke pé, Abba, Baba. Ẹmí tikararẹ̀ li o mba ẹmí wa jẹrí pe, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe
Rom 8:11-16 Yoruba Bible (YCE)
Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kò sí ohunkohun mọ́ tí ó mú wa ní túlààsì pé kí á máa hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí. Nítorí bí ẹ bá hùwà bí àwọn tí ẹran-ara ń darí, kíkú ni ẹ óo kú dandan. Ṣugbọn tí ẹ bá ń rìn lọ́nà ti Ẹ̀mí, tí ẹ kò sì hu ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ẹ óo yè. Nítorí àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń darí ni ọmọ Ọlọrun. Ẹ̀mí tí Ọlọrun fun yín kì í ṣe èyí tí yóo tún sọ yín di ẹrú, tí yóo sì máa mu yín bẹ̀rù. Ṣugbọn Ẹ̀mí tí ó sọ yín di ọmọ ni ẹ gbà. Ẹ̀mí yìí náà ni ó jẹ́ kí á lè máa ké pe Ọlọrun pé, “Baba! Baba wa!” Ẹ̀mí kan náà ní ń sọ sí wa lọ́kàn pé ọmọ Ọlọrun ni wá.
Rom 8:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jesu kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, ẹni tí ó jí Kristi Jesu dìde kúrò nínú òkú, yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tí ń gbé inú yín sọ ara kíkú yín di ààyè pẹ̀lú. Nítorí náà ará a ni ojúṣe láti ṣe, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa nǹkan tí ara, tí a ó fi máa gbé nípa ti ara. Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì ṣègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ń gbé nípa ti ara, ẹ̀yin yóò kú, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yín bá ń gbé nípa ti Ẹ̀mí, ẹ ó pa iṣẹ́ ti ara run, ẹ̀yin yóò yè. Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run. Nítorí ẹ̀yin kò tún gba ẹ̀mí ẹrú láti máa bẹ̀rù mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, nípa èyí tí àwa fi ń ké pé “Ábbà, Baba.” Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, nítòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.