Rom 7:7-13
Rom 7:7-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ awa o ha ti wi? ofin ha iṣe ẹ̀ṣẹ bi? Ki a má ri. Ṣugbọn emi kò ti mọ̀ ẹ̀ṣẹ, bikoṣepe nipa ofin: emi kò sá ti mọ̀ ojukokoro, bikoṣe bi ofin ti wipe, Iwọ kò gbọdọ ṣojukòkoro. Ẹ̀ṣẹ si ti ipa ofin ri aye, o ṣiṣẹ onirũru ifẹkufẹ ninu mi. Nitori laisi ofin, ẹ̀ṣẹ kú. Emi si ti wà lãye laisi ofin nigbakan rì: ṣugbọn nigbati ofin de, ẹ̀ṣẹ sọji, emi si kú. Ofin ti a ṣe fun ìye, eyi li emi si wa ri pe o jẹ fun ikú. Nitori ẹ̀ṣẹ ti ipa ofin ri aye, o tàn mi jẹ, o si ti ipa rẹ̀ lù mi pa. Bẹ̃ni mimọ́ li ofin, mimọ́ si li aṣẹ, ati ododo, ati didara. Njẹ ohun ti o dara ha di ikú fun mi bi? Ki a má ri. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ ki o le farahan bi ẹ̀ṣẹ o nti ipa ohun ti o dara ṣiṣẹ́ ikú ninu mi, ki ẹ̀ṣẹ le ti ipa ofin di buburu rekọja.
Rom 7:7-13 Yoruba Bible (YCE)
Kí ni kí á wá wí wàyí ò? Ṣé Òfin wá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o! Ṣugbọn ṣá, èmi kì bá tí mọ ẹ̀ṣẹ̀ bí Òfin kò bá fi í hàn mí. Bí àpẹẹrẹ, ǹ bá tí mọ ojúkòkòrò bí Òfin kò bá sọ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.” Àṣẹ yìí ni ẹ̀ṣẹ̀ rí dìrọ̀ mọ́ láti fi ṣiṣẹ́. Ó ń fi èrò oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí mi lọ́kàn. Bí a bá mú òfin kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ di òkú. Nígbà kan rí mò ń gbé ìgbésí-ayé mi láìsí òfin. Ṣugbọn nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ yọjú pẹlu, ni mo bá kú. Òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá, ni ó wá di ọ̀ràn ikú fún mi. Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ rí ohun dìrọ̀ mọ́ ninu òfin, ó tàn mí jẹ, ó sì pa mí kú. Dájú, ohun mímọ́ ni Òfin, àwọn àṣẹ tí ó wà ninu rẹ̀ náà sì jẹ́ ohun mímọ́, ohun tí ó tọ́, tí ó sì dára. Ǹjẹ́ ohun tí ó dára yìí ni ó ṣe ikú pa mí? Rárá o! Ẹ̀ṣẹ̀ níí ṣekú pani. Kí ẹ̀ṣẹ̀ lè fara rẹ̀ hàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó lo ohun tí ó dára láti pa mí kú, báyìí, ó hàn gbangba pé ibi gan-an ni ẹ̀ṣẹ̀ í ṣe, nítorí ó kó sábẹ́ òfin láti ṣe ibi.
Rom 7:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí, nígbà náà? Òfin ha ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, bí kò ṣe nípa òfin. Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò, bí kò ṣe bí òfin ti wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.” Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ sì ti ipa òfin rí ààyè ṣiṣẹ́ onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú mi. Nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ikú. Èmi sì ti wà láààyè láìsí òfin nígbà kan rí; ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú. Mo ṣàkíyèsí pé òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá ni ó padà mú ikú wá. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí ààyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin ṣe ikú pa mi. Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára. Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá.