Rom 7:14-16
Rom 7:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori awa mọ̀ pe ohun ẹmí li ofin: ṣugbọn ẹni ti ara li emi, ti a ti tà sabẹ ofin. Nitori ohun ti emi nṣe, emi kò mọ̀: nitori ki iṣe ohun ti mo fẹ li emi nṣe; ṣugbọn ohun ti mo korira, li emi nṣe. Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ eyini li emi nṣe, mo gba pe ofin dara.
Rom 7:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Àwa mọ̀ dájú pé Òfin jẹ́ nǹkan ti Ẹ̀mí. Ṣugbọn èmi jẹ́ eniyan ẹlẹ́ran-ara, tí a ti tà lẹ́rú fún ẹ̀ṣẹ̀. Ìwà mi kò yé èmi alára; nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan tí mo bá fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, àwọn nǹkan tí mo kórìíra gan-an ni mò ń ṣe. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ń ṣe àwọn nǹkan tí n kò fẹ́, mò ń jẹ́rìí sí i pé Òfin jẹ́ ohun tí ó dára.
Rom 7:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin: ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń ṣe. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ ṣe gan an n kò ṣe é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni mo ń ṣe. Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára.