Rom 7:1-6
Rom 7:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
TABI ẹnyin ha ṣe alaimọ̀, ará (nitori awọn ti o mọ̀ ofin li emi mba sọrọ), pe ofin ni ipa lori enia niwọn igbati o ba wà lãye? Nitori obinrin ti o ni ọkọ, ìwọn igbati ọkọ na wà lãye, a fi ofin dè e mọ́ ọkọ na; ṣugbọn bi ọkọ na ba kú, a tú u silẹ kuro ninu ofin ọkọ na. Njẹ bi o ba ni ọkọ miran nigbati ọkọ rẹ̀ wà lãye, panṣaga li a o pè e: ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o bọ lọwọ ofin na; ki yio si jẹ panṣaga bi o ba ni ọkọ miran. Bẹ̃li ẹnyin ará mi, ẹnyin pẹlu ti di okú si ofin nipa ara Kristi: ki ẹnyin kì o le ni ẹlomiran, ani ẹniti a jinde kuro ninu okú, ki awa ki o le so eso fun Ọlọrun. Nitori igbati awa wà nipa ti ara, ifẹkufẹ ẹ̀ṣẹ, ti o wà nipa ofin, o nṣiṣẹ ninu awọn ẹ̀ya ara wa lati so eso si ikú. Ṣugbọn nisisiyi a fi wa silẹ kuro ninu ofin, nitori a ti kú si eyiti a ti dè wa sinu rẹ̀: ki awa ki o le mã sìn li ọtun Ẹmí, ki o má ṣe ni ode ara ti atijọ.
Rom 7:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará mi, ohun tí mò ń wí yìí kò ṣe àjèjì si yín (nítorí ẹ̀yin náà mọ òfin), pé òfin de eniyan níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè nìkan. Bí àpẹẹrẹ, òfin igbeyawo de abilekọ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, òfin tí ó de obinrin náà mọ́ ọkọ rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ mọ́. Wàyí ò, bí obinrin náà bá lọ bá ọkunrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè, alágbèrè ni a óo pè é. Ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ bá ti kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin igbeyawo, kì í ṣe àgbèrè mọ́, bí ó bá lọ fẹ́ ọkọ mìíràn. Bẹ́ẹ̀ náà ni, ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin náà ti kú ní ti Òfin, nígbà tí ẹ di ara kan náà pẹlu Kristi. Ẹ ti ní ọkọ mìíràn, àní, ẹni tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kí á lè sin Ọlọrun lọ́nà tí yóo yọrí sí rere. Tẹ́lẹ̀ rí, nígbà tí a ti ń ṣe ìfẹ́ inú wa bí ẹlẹ́ran-ara, èrò ọkàn wa a máa fà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Òfin dá wa lẹ́kun rẹ̀, láti tì wá sí ohun tí àyọrísí rẹ̀ jẹ́ ikú. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti bọ́ kúrò lábẹ́ Òfin. A ti kú sí ohun tí ó dè wá. Báyìí, a kò sin Ọlọrun lọ́nà àtijọ́ mọ́, àní lọ́nà ti Òfin àkọsílẹ̀, ṣugbọn ní ọ̀nà titun ti Ẹ̀mí.
Rom 7:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin kò ha mọ̀, ara: nítorí èmí bá àwọn tí ó mọ òfin sọ̀rọ̀ pé, òfin ní ipá lórí ènìyàn níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láààyè nìkan? Fún àpẹẹrẹ, nípa òfin ní a de obìnrin mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ náà wà láààyè, ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a tú u sílẹ̀ kúrò nínú òfin ìgbéyàwó náà. Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láààyè, panṣágà ní a ó pè é. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóò sì jẹ́ panṣágà bí ó bá ní ọkọ mìíràn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run Nítorí ìgbà tí a wa nípa ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípa ti òfin, ma ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tí a sì ń so èso tí ó yẹ fún ikú. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa kíkú ohun tó so wá pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í ṣe ní ìlànà àtijọ́ tí ìwé òfin gùnlé.