Rom 6:8-10
Rom 6:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi awa ba bá Kristi kú, awa gbagbọ́ pe awa ó si wà lãye pẹlu rẹ̀: Nitori awa mọ̀ pé bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú, kò ni ikú mọ́; ikú kò ni ipa lori rẹ̀ mọ́. Nitori iku ti o kú, o kú si ẹ̀ṣẹ lẹ̃kan: nitori wiwà ti o wà lãye, o wà lãye si Ọlọrun.
Rom 6:8-10 Yoruba Bible (YCE)
Bí a bá jọ bá Jesu kú, a ní igbagbọ pé a óo jọ bá Jesu yè. A mọ̀ pé Kristi tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kò tún ní kú mọ́; ikú kò sì lè jọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́. Kíkú tí ó kú jẹ́ pé ó ti kú ikú tí ó níláti kú lẹ́ẹ̀kan; yíyè tí ó yè, ó yè fún ògo Ọlọrun.
Rom 6:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí, bí àwa bá kú pẹ̀lú Kristi àwa gbàgbọ́ pé àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí àwa mọ̀ pé Kristi ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́. Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, láti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láààyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.