Rom 6:4-8
Rom 6:4-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀: pe gẹgẹ bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba bẹ̃ni ki awa pẹlu ki o mã rìn li ọtun ìwa. Nitori bi a ba ti so wa pọ̀ pẹlu rẹ̀ nipa afarawe ikú rẹ̀, a o si so wa pọ pẹlu nipa afarawe ajinde rẹ̀: Nitori awa mọ eyi pe, a kàn ogbologbo ọkunrin wa mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ki a le pa ara ẹ̀ṣẹ run, ki awa maṣe sìn ẹ̀ṣẹ mọ́. Nitori ẹniti o kú, o bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ. Ṣugbọn bi awa ba bá Kristi kú, awa gbagbọ́ pe awa ó si wà lãye pẹlu rẹ̀
Rom 6:4-8 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jọ sin wá pọ̀ nígbà tí wọ́n rì wá bọmi, tí wọ́n sọ wá di òkú, kí àwa náà lè máa gbé ìgbé-ayé titun gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun baba ògo ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú. Bí a bá sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu Jesu ninu ikú, a óo sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu rẹ̀ ninu ajinde. Ẹ jẹ́ kí òye yìí yé wa: a ti kan ẹni àtijọ́ tí àwọn eniyan mọ̀ wá sí mọ́ agbelebu pẹlu Jesu, kí ẹran-ara tí eniyan fi ń dẹ́ṣẹ̀ lè di òkú, kí á lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí ẹni tí ó ti kú ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Bí a bá jọ bá Jesu kú, a ní igbagbọ pé a óo jọ bá Jesu yè.
Rom 6:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun. Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde. Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́. Nísinsin yìí, bí àwa bá kú pẹ̀lú Kristi àwa gbàgbọ́ pé àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀.