Rom 6:3-6
Rom 6:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tabi ẹ kò mọ̀ pe, gbogbo wa ti a ti baptisi sinu Kristi Jesu, a ti baptisi wa sinu ikú rẹ̀? Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀: pe gẹgẹ bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba bẹ̃ni ki awa pẹlu ki o mã rìn li ọtun ìwa. Nitori bi a ba ti so wa pọ̀ pẹlu rẹ̀ nipa afarawe ikú rẹ̀, a o si so wa pọ pẹlu nipa afarawe ajinde rẹ̀: Nitori awa mọ eyi pe, a kàn ogbologbo ọkunrin wa mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ki a le pa ara ẹ̀ṣẹ run, ki awa maṣe sìn ẹ̀ṣẹ mọ́.
Rom 6:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Àbí ẹ kò mọ̀ pé gbogbo àwa tí a ti rì bọmi lórúkọ Jesu a ti kú bí Jesu ti kú? Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jọ sin wá pọ̀ nígbà tí wọ́n rì wá bọmi, tí wọ́n sọ wá di òkú, kí àwa náà lè máa gbé ìgbé-ayé titun gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun baba ògo ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú. Bí a bá sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu Jesu ninu ikú, a óo sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu rẹ̀ ninu ajinde. Ẹ jẹ́ kí òye yìí yé wa: a ti kan ẹni àtijọ́ tí àwọn eniyan mọ̀ wá sí mọ́ agbelebu pẹlu Jesu, kí ẹran-ara tí eniyan fi ń dẹ́ṣẹ̀ lè di òkú, kí á lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.
Rom 6:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tàbí ẹyin kò mọ pé gbogbo wa ti a ti bamitiisi wa sínú Jesu Kristi ni a ti bamitiisi sínú ikú rẹ. Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun. Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde. Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.