Rom 6:16-18
Rom 6:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin kò mọ̀ pe, ẹniti ẹnyin ba jọwọ ara nyin lọwọ fun bi ẹrú lati mã gbọ́ tirẹ̀, ẹrú ẹniti ẹnyin ba gbọ tirẹ̀ li ẹnyin iṣe; ibãṣe ti ẹ̀ṣẹ sinu ikú, tabi ti igbọran si ododo? Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun pe, bi ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ rí, ẹnyin jẹ olugbọran lati ọkàn wá si apẹrẹ ẹkọ ti a fi nyin le lọwọ. Bi a si ti sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ẹnyin di ẹrú ododo.
Rom 6:16-18 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kò mọ̀ pé ẹrú ẹni tí ẹ bá ń gbọ́ràn sí lẹ́nu lẹ jẹ́, ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fara yín ṣẹrú fún, tí ẹ sì ń jíṣẹ́ fún? Ẹ lè fi ara yín ṣẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀, kí ó fikú san án fun yín; ẹ sì lè fìgbọràn ṣọ̀gá fún ara yín, kí ó sì fun yín ní ìdáláre. Ọpẹ́ ni fỌlọrun, nítorí pé ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ti wá ń fi tọkàntọkàn gba irú ẹ̀kọ́ tí a gbé kalẹ̀ níwájú yín. A ti tu yín sílẹ̀ ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ti di ẹrú iṣẹ́ rere.
Rom 6:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ ti o yọrí si ikú tàbí ìgbọ́ràn ti o yọrí sí ìdáláre. Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fi ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ẹ̀yin ti jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ rí, ẹ̀yin jẹ́ olùgbọ́ran láti ọkàn wá sí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́. Nísinsin yìí, ẹ ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo.