Rom 5:8-11
Rom 5:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa. Melomelo si ni, ti a da wa lare nisisiyi nipa ẹ̀jẹ rẹ̀, li a o gbà wa là kuro ninu ibinu nipasẹ rẹ̀. Njẹ bi, nigbati awa wà li ọtá, a mu wa ba Ọlọrun làja nipa ikú Ọmọ rẹ̀, melomelo, nigbati a là wa ni ìja tan, li a o gbà wa là nipa ìye rẹ̀. Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn awa nṣogo ninu Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti awa ti ri ìlaja gbà nisisiyi.
Rom 5:8-11 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn Ọlọrun fihàn wá pé òun fẹ́ràn wa ní ti pé nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa. Bí ó bá lè kú fún wa nígbà tí a sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, nisinsinyii tí Ọlọrun ti dá wa láre nítorí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, a óo sì torí rẹ̀ gbà wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀. Bí ikú Ọmọ Ọlọrun bá sọ àwa tí a jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun di ọ̀rẹ́ rẹ̀, nígbà yìí tí a wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun tán, ajinde ọmọ rẹ̀ yóo gbà wá là ju tàtẹ̀yìnwá lọ. Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣugbọn à ń yọ̀ ninu Ọlọrun nítorí ohun tí ó ṣe nípa Oluwa wa Jesu Kristi, ẹni tí ó sọ wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun ní àkókò yìí.
Rom 5:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa. Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.