Rom 5:3-5
Rom 5:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn awa si nṣogo ninu wahalà pẹlu: bi a ti mọ̀ pe wahalà nṣiṣẹ sũru; Ati sũru nṣiṣẹ iriri; ati iriri ni nṣiṣẹ ireti: Ireti kì si idojuti ni; nitori a ti tan ifẹ Ọlọrun ká wa lọ́kàn lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ wá ti a fifun wa.

Rom 5:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Èyí nìkan kọ́. A tún ń fi àwọn ìṣòro wa ṣe ọlá, nítorí a mọ̀ pé àyọrísí ìṣòro ni ìfaradà; àyọrísí ìfaradà ni ìyege ìdánwò; àyọrísí ìyege ìdánwò ni ìrètí. Ìrètí irú èyí kì í ṣe ohun tí yóo dójú tì wá, nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọrun dà sí wa lọ́kàn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fún wa.
Rom 5:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.