Rom 5:18-21
Rom 5:18-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ bi nipa ẹ̀ṣẹ kan idajọ de bá gbogbo enia si idalẹbi; gẹgẹ bẹ̃ni nipa iwa ododo kan, ẹ̀bun ọfẹ de sori gbogbo enia fun idalare si ìye. Nitori gẹgẹ bi nipa aigbọran enia kan, enia pupọ di ẹlẹṣẹ bẹ̃ ni nipa igbọran ẹnikan, a o sọ enia pupọ di olododo. Ṣugbọn ofin bọ si inu rẹ̀, ki ẹ̀ṣẹ le di pupọ. Ṣugbọn nibiti ẹ̀ṣẹ di pupọ, ore-ọfẹ di pupọ rekọja, Pe, gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti jọba nipa ikú, bẹni ki ore-ọfẹ si le jọba nipa ododo titi ìye ainipẹkun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa.
Rom 5:18-21 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, bí òfin tí ẹnìkan rú ṣe ti gbogbo ọmọ aráyé sinu ìdájọ́ ikú, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ rere ẹnìkan yóo yọ gbogbo ọmọ aráyé ninu ìdájọ́ ikú sí ìyè. Bí a ti sọ gbogbo eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀ nítorí àìgbọràn ẹnìkan, bẹ́ẹ̀ náà ni a óo torí ìgbọràn ẹnìkan dá gbogbo eniyan láre. Ọ̀nà ẹ̀bùrú ni òfin gbà wọlé, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè pọ̀ jantirẹrẹ. Níbi tí ẹ̀ṣẹ̀ bá sì ti pọ̀, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun a máa pọ̀ ju bí ẹ̀ṣẹ̀ ti pọ̀ tó lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ikú ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ di ọba, bẹ́ẹ̀ ni ìdáláre náà ń fi oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jọba, ó sì mú wa wọnú ìyè ainipẹkun nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.
Rom 5:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè. Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo. Ṣùgbọ́n òfin bọ́ sí inú rẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè di púpọ̀, ṣùgbọ́n ni ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, oore-ọ̀fẹ́ di púpọ̀ rékọjá. Pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jẹ ọba nípa ikú bẹ́ẹ̀ ni kí oore-ọ̀fẹ́ sì lè jẹ ọba nípa òdodo títí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa.