Rom 4:1-5
Rom 4:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ kili awa o ha wipe Abrahamu, baba wa nipa ti ara, ri? Nitori bi a ba da Abrahamu lare nipa iṣẹ, o ni ohun iṣogo; ṣugbọn kì iṣe niwaju Ọlọrun. Iwe-mimọ́ ha ti wi? Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u. Njẹ fun ẹniti o ṣiṣẹ a kò kà ère na si ore-ọfẹ bikoṣe si gbese. Ṣugbọn fun ẹniti kò ṣiṣẹ, ti o si ngbà ẹniti o nda enia buburu lare gbọ́, a kà igbagbọ́ rẹ̀ si ododo.
Rom 4:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Kí ni kí á wí nípa Abrahamu baba-ńlá wa nípa ti ara? Kí ni ìrírí rẹ̀? Bí ó bá jẹ́ pé nítorí ohun tí ó ṣe ni Ọlọrun fi dá a láre, ìwọ̀nba ni ohun tí ó lè fi ṣe ìgbéraga. Ṣugbọn kò lè fọ́nnu níwájú Ọlọrun. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere.” A kò lè pe èrè tí òṣìṣẹ́ bá gbà ní ẹ̀bùn; ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni. Ṣugbọn ẹni tí kò ṣe nǹkankan, ṣugbọn tí ó ṣá ní igbagbọ sí ẹni tí ó ń dá ẹni tí kò yẹ láre, Ọlọrun kà á sí ẹni rere nípa igbagbọ rẹ̀.
Rom 4:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Abrahamu, baba wa ti o ṣàwárí èyí? Májẹ̀mú láéláé jẹ́rìí sí i wí pé, a gba Abrahamu là nípa ìgbàgbọ́. Nítorí bí a bá dá Abrahamu láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo; ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ ha ti wí? “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.” Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ṣiṣẹ́, a kò ka èrè náà sí oore-ọ̀fẹ́ bí kò ṣe sí ẹ̀tọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́, tí ó sì ń gba ẹni tí ó ń dá ènìyàn búburú láre gbọ́, a ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo.