Rom 4:1-3
Rom 4:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ kili awa o ha wipe Abrahamu, baba wa nipa ti ara, ri? Nitori bi a ba da Abrahamu lare nipa iṣẹ, o ni ohun iṣogo; ṣugbọn kì iṣe niwaju Ọlọrun. Iwe-mimọ́ ha ti wi? Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u.
Rom 4:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Kí ni kí á wí nípa Abrahamu baba-ńlá wa nípa ti ara? Kí ni ìrírí rẹ̀? Bí ó bá jẹ́ pé nítorí ohun tí ó ṣe ni Ọlọrun fi dá a láre, ìwọ̀nba ni ohun tí ó lè fi ṣe ìgbéraga. Ṣugbọn kò lè fọ́nnu níwájú Ọlọrun. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere.”
Rom 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Abrahamu, baba wa ti o ṣàwárí èyí? Májẹ̀mú láéláé jẹ́rìí sí i wí pé, a gba Abrahamu là nípa ìgbàgbọ́. Nítorí bí a bá dá Abrahamu láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo; ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ ha ti wí? “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”