Rom 3:21-31

Rom 3:21-31 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn ní àkókò yìí, ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre ti hàn láìsí Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ti Òfin ati ti àwọn wolii Ọlọrun jẹ́rìí sí i. Gbogbo àwọn tí ó bá gba Jesu gbọ́ yóo yege lọ́dọ̀ Ọlọrun láìsí ìyàtọ̀ kan. Nítorí gbogbo eniyan ló ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọrun. Gbogbo wọn ni Ọlọrun ti ṣe lóore: ó dá wọn láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa ìràpadà tí Kristi Jesu ṣe. Jesu yìí ni Ọlọrun fi ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́, nípa ikú rẹ̀. Èyí ni láti fi ọ̀nà tí Ọlọrun yóo fi dá eniyan láre hàn, nítorí pé ó fi ojú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dá, nípa ìyọ́nú rẹ̀, kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn ní àkókò yìí, kí ó lè hàn pé olódodo ni òun, ati pé òun ń dá ẹni tí ó bá gba Jesu gbọ́ láre. Ààyè ìgbéraga dà? Kò sí rárá. Nípa irú ìlànà wo ni kò fi sí mọ́? Nípa iṣẹ́ Òfin ni bí? Rárá o! Nípa ìlànà ti igbagbọ ni. Nítorí ohun tí a rí ni pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun ń dá eniyan láre, kì í ṣe nípa pípa Òfin mọ́. Àbí ti àwọn Juu nìkan ni Ọlọrun, kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù? Dájúdájú Ọlọrun àwọn Juu ati ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ni. Nígbà tí ó jẹ́ pé Ọlọrun kanṣoṣo ni ó wà, òun ni ó sì ń dá àwọn tí ó kọlà láre nípa igbagbọ, tí ó tún ń dá àwọn tí kò kọlà láre nípa igbagbọ bákan náà. Ṣé Òfin wá di òtúbáńtẹ́ nítorí igbagbọ ni? Rárá o! A túbọ̀ fi ìdí Òfin múlẹ̀ ni.

Rom 3:21-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rìí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì; Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni. Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run: Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu: Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run: Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́. Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́. Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin. Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú: Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nípa ìgbàgbọ́ wọn. Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i: ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.