Rom 3:10-20
Rom 3:10-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan: Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun. Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan. Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn: Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro: Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ: Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn: Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀: Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn. Awa si mọ̀ pe ohunkohun ti ofin ba wi, o nwi fun awọn ti o wà labẹ ofin: ki gbogbo ẹnu ki o le pamọ́, ati ki a le mu gbogbo araiye wá sabẹ idajọ Ọlọrun. Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá.
Rom 3:10-20 Yoruba Bible (YCE)
Ó wà ní àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ pé, “Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ olódodo; kò sí ẹnìkankan. Kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ti yapa kúrò lójú ọ̀nà, gbogbo wọn kò níláárí mọ́, kò sí ẹni tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan. Ibojì tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀nà ọ̀fun wọn, ẹ̀tàn kún ẹnu wọn; oró paramọ́lẹ̀ wà létè wọn; ẹnu wọn kún fún èpè ati ọ̀rọ̀ burúkú. Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀nà jamba ati òṣì ni wọ́n ń rìn. Wọn kò mọ ọ̀nà alaafia. Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ní ọkàn wọn.” A mọ̀ pé ohunkohun tí Òfin bá wí, ó wà fún àwọn tí ó mọ Òfin ni, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rí àwáwí wí, kí gbogbo aráyé lè wà lábẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, bí a bá mú Òfin tí a fi díwọ̀n iṣẹ́ ọmọ eniyan, kò sí ẹ̀dá kan tí a óo dá láre níwájú Ọlọrun. Nítorí òfin níí mú kí eniyan mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀.
Rom 3:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan Kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run. Gbogbo wọn ni ó ti yapa, wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè; kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.” “Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn: ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.” “Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.” “Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.” “Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀: ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn. Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:” “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.” Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.