Rom 3:1-9

Rom 3:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀nà wo wá ni àwọn Juu fi sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ? Kí ni anfaani ìkọlà? Ó pọ̀ pupọ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Ekinni, àwọn Juu ni Ọlọrun fún ní ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Ẹ lè wá sọ pé, “Anfaani wo ni ó wà ninu èyí nígbà tí àwọn mìíràn ninu wọn kò gbàgbọ́? Ǹjẹ́ aigbagbọ wọn kò sọ ìṣòtítọ́ Ọlọrun di òtúbáńtẹ́?” Rárá o! Ọlọrun níláti jẹ́ olóòótọ́ bí gbogbo eniyan bá tilẹ̀ di onírọ́. Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Kí ìwọ Ọlọrun lè jẹ́ olódodo ninu ọ̀rọ̀ rẹ, kí o lè borí nígbà tí wọ́n bá pè ọ́ lẹ́jọ́.” Bí aiṣododo wa bá mú kí òdodo Ọlọrun fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ni kí á wá wí? Ṣé Ọlọrun kò ṣe ẹ̀tọ́ láti bínú sí wa ni? (Mò ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé eniyan ni Ọlọrun.) Rárá o! Bí Ọlọrun kò bá ní ẹ̀tọ́ láti bínú, báwo ni yóo ṣe wá ṣe ìdájọ́ aráyé? Bí aiṣotitọ mi bá mú kí ògo òtítọ́ Ọlọrun túbọ̀ hàn, kí ni ṣe tí a tún fi ń dá mi lẹ́bi bí ẹlẹ́ṣẹ̀? Ṣé, “Kí á kúkú máa ṣe ibi kí rere lè ti ibẹ̀ jáde?” Bí àwọn onísọkúsọ kan ti ń sọ pé à ń sọ. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yẹ fún ìdálẹ́bi. Kí ni kí á rí dìmú ninu ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé àwa Juu sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ ni? Rárá o! Nítorí a ti wí ṣáájú pé ati Juu ati Giriki, gbogbo wọn ni ó wà ní ìkáwọ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Rom 3:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ? Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́. Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí? Kí a má rí! Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtítọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.” Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí? Ọlọ́run ha jẹ́ àìṣòdodo bí? Nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn (Mo fi ṣe àkàwé bí ènìyàn). Kí a má rí i. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé? Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀? Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá? Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀; ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ; àwọn ẹni tí ìdálẹ́bi wọn tọ́. Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn ju wọn lọ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá: nítorí a fihàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀