Rom 3:1-4
Rom 3:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ anfani ki ha ni ti Ju? tabi kini ère ilà kíkọ? Pipọ lọna gbogbo; ekini, nitoripe awọn li a fi ọ̀rọ Ọlọrun le lọwọ. Njẹ ki ha ni bi awọn kan jẹ alaigbagbọ́? aigbagbọ́ wọn yio ha sọ otitọ Ọlọrun di asan bi? Ki a má ri: k'Ọlọrun jẹ olõtọ, ati olukuluku enia jẹ eke; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ki a le da ọ lare ninu ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn ki iwọ le ṣẹgun nigbati iwọ ba wá si idajọ.
Rom 3:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀nà wo wá ni àwọn Juu fi sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ? Kí ni anfaani ìkọlà? Ó pọ̀ pupọ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Ekinni, àwọn Juu ni Ọlọrun fún ní ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Ẹ lè wá sọ pé, “Anfaani wo ni ó wà ninu èyí nígbà tí àwọn mìíràn ninu wọn kò gbàgbọ́? Ǹjẹ́ aigbagbọ wọn kò sọ ìṣòtítọ́ Ọlọrun di òtúbáńtẹ́?” Rárá o! Ọlọrun níláti jẹ́ olóòótọ́ bí gbogbo eniyan bá tilẹ̀ di onírọ́. Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Kí ìwọ Ọlọrun lè jẹ́ olódodo ninu ọ̀rọ̀ rẹ, kí o lè borí nígbà tí wọ́n bá pè ọ́ lẹ́jọ́.”
Rom 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ? Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́. Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí? Kí a má rí! Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtítọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”