Rom 16:1-2
Rom 16:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
MO fi Febe, arabinrin wa, le nyin lọwọ ẹniti iṣe diakoni ijọ ti o wà ni Kenkrea: Ki ẹnyin le gbà a ninu Oluwa, bi o ti yẹ fun awọn enia mimọ́, ki ẹnyin ki o si ràn a lọwọ iṣẹkiṣẹ ti o nwá ni iranlọwọ lọdọ nyin: nitori on pẹlu ti nṣe oluranlọwọ fun ẹni pipọ, ati fun emi na pẹlu.
Rom 16:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Mo fẹ́ kí ẹ gba Febe bí arabinrin wa, ẹni tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọ tí ó wà ní Kẹnkiria. Ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀ ní orúkọ Kristi gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ onigbagbọ. Kí ẹ ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nàkọ́nà tí ó bá fẹ́; nítorí ó jẹ́ ẹni tí ó ran ọpọlọpọ eniyan ati èmi pàápàá lọ́wọ́.
Rom 16:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo fi Febe arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díákónì nínú ìjọ tí ó wà ní Kenkerea. Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú.