Rom 15:1-3
Rom 15:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ o yẹ ki awa ti o lera iba mã ru ẹrù ailera awọn alailera, ki a má si ṣe ohun ti o wù ara wa. Jẹ ki olukuluku wa ki o mã ṣe ohun ti o wù ọmọnikeji rẹ̀ si rere rẹ̀ lati gbe e ró. Nitori Kristi pẹlu kò ṣe ohun ti o wù ara rẹ̀; ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹ̀gan awọn ti ngàn ọ ṣubu lù mi.
Rom 15:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ó yẹ kí àwa tí a jẹ́ alágbára ninu igbagbọ máa fara da àwọn nǹkan tí àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ bá ń ṣiyèméjì lé lórí. A kò gbọdọ̀ máa tẹ́ ara wa nìkan lọ́rùn. Olukuluku wa níláti máa ṣe ohun tí yóo tẹ́ ẹnìkejì rẹ̀ lọ́rùn fún ire rẹ̀ ati fún ìdàgbàsókè rẹ̀. Nítorí Kristi kò ṣe nǹkan tí ó tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Dípò bẹ́ẹ̀ ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Èmi ni ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ó ń gàn ọ́ rẹ́ lára.”
Rom 15:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má sì ṣe ohun tí ó wu ara wa. Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró. Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe ohun tí ó wu ara rẹ̀, ṣùgbọ́n, bí a ti kọ ọ́ pé: “Ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mi.”