Rom 15:1-21

Rom 15:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ o yẹ ki awa ti o lera iba mã ru ẹrù ailera awọn alailera, ki a má si ṣe ohun ti o wù ara wa. Jẹ ki olukuluku wa ki o mã ṣe ohun ti o wù ọmọnikeji rẹ̀ si rere rẹ̀ lati gbe e ró. Nitori Kristi pẹlu kò ṣe ohun ti o wù ara rẹ̀; ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹ̀gan awọn ti ngàn ọ ṣubu lù mi. Nitori ohunkohun ti a ti kọ tẹlẹ, a ti kọ ọ fun kíkọ wa, pe nipa sũru ati itunu iwe-mimọ́ ki a le ni ireti. Njẹ ki Ọlọrun sũru ati itunu ki o fi fun nyin lati ni inu kan si ara nyin gẹgẹ bi Kristi Jesu: Ki ẹnyin ki o le fi ọkàn kan ati ẹnu kan yìn Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa, logo. Nitorina ẹ gbá ara nyin mọra, gẹgẹ bi Kristi ti gbá wa mọra fun ogo Ọlọrun. Mo si wipe, a ti fi Jesu Kristi ṣe iranṣẹ ikọla nitori otitọ Ọlọrun, ki o ba le mu awọn ileri na duro ti a ti ṣe fun awọn baba, Ati ki awọn Keferi ki o le yìn Ọlọrun logo nitori ãnu rẹ̀; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori eyi li emi ó ṣe yin ọ lãrin awọn Keferi, emi o si kọrin si orukọ rẹ. O si tún wipe, Ẹnyin Keferi, ẹ mã yọ̀ pẹlu awọn enia rẹ̀. Ati pẹlu, Ẹ yìn Oluwa gbogbo ẹnyin Keferi; ẹ si kokikí rẹ̀, ẹnyin enia gbogbo. Isaiah si tún wipe, Gbòngbo Jesse kan mbọ̀ wá, ati ẹniti yio dide ṣe akoso awọn Keferi; on li awọn Keferi yio ni ireti si. Njẹ ki Ọlọrun ireti ki o fi gbogbo ayọ̀ on alafia kún nyin ni gbigbagbọ, ki ẹnyin ki o le pọ̀ ni ireti nipa agbara Ẹmí Mimọ́. Ará mi, o si da emi tikarami loju nipa ti nyin pe, ẹnyin si kun fun ore, a si fi gbogbo imọ kún nyin, ẹnyin si le mã kìlọ fun ara nyin. Ṣugbọn, ará mi, mo fi igboiya kọwe si nyin li ọna kan, bi ẹni tun nrán nyin leti, nitori ore-ọfẹ ti a ti fifun mi lati ọdọ Ọlọrun wá, Ki emi ki o le ṣe iranṣẹ Jesu Kristi si awọn Keferi, lati ta ọrẹ ihinrere Ọlọrun, ki ọrẹ awọn Keferi ki o le di itẹwọgbà, ti a sọ di mimọ́ nipa Ẹmí Mimọ́. Nitorina mo ni iṣogo ninu Jesu Kristi nipa ohun ti iṣe ti Ọlọrun. Emi kò sá gbọdọ sọ ohun kan ninu eyi ti Kristi kò ti ọwọ́ ṣe, si igbọran awọn Keferi nipa ọ̀rọ ati iṣe, Nipa agbara iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, nipa agbara Ẹmí Ọlọrun; tobẹ̃ lati Jerusalemu ati yiká kiri ani titi fi de Illirikoni, mo ti wasu ihinrere Kristi ni kikun. Mo du u lati mã wasu ihinrere na, kì iṣe nibiti a gbé ti da orukọ Kristi ri, ki emi ki o máṣe mọ amọle lori ipilẹ ẹlomiran. Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Awọn ẹniti a kò ti sọ̀rọ rẹ̀ fun, nwọn ó ri i: ati awọn ti kò ti gbọ́, òye yio yé wọn.

Rom 15:1-21 Yoruba Bible (YCE)

Ó yẹ kí àwa tí a jẹ́ alágbára ninu igbagbọ máa fara da àwọn nǹkan tí àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ bá ń ṣiyèméjì lé lórí. A kò gbọdọ̀ máa tẹ́ ara wa nìkan lọ́rùn. Olukuluku wa níláti máa ṣe ohun tí yóo tẹ́ ẹnìkejì rẹ̀ lọ́rùn fún ire rẹ̀ ati fún ìdàgbàsókè rẹ̀. Nítorí Kristi kò ṣe nǹkan tí ó tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Dípò bẹ́ẹ̀ ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Èmi ni ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ó ń gàn ọ́ rẹ́ lára.” Nítorí fún àtikọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ni a ṣe kọ ohunkohun tí a ti kọ tẹ́lẹ̀, ìdí rẹ̀ ni pé kí ìgboyà ati ìwúrí tí Ìwé Mímọ́ ń fún wa lè fún wa ní ìrètí. Kí Ọlọrun, tí ó ń fún wa ní ìrọ́jú ati ìwúrí, jẹ́ kí ẹ ní ọkàn kan náà sí ara yín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Kristi Jesu, kí ẹ fi inú kan ati ohùn kan yin Ọlọrun ati Baba Oluwa Jesu Kristi. Nítorí náà, ẹ fa ara yín mọ́ra gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà yín, kí á lè fi ògo fún Ọlọrun. Ohun tí mò ń sọ ni pé Kristi ti di iranṣẹ fún àwọn tí ó kọlà, láti mú òtítọ́ Ọlọrun ṣẹ, kí ó lè mú àwọn ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba-ńlá ṣẹ, ati láti jẹ́ kí àwọn tí kò kọlà lè yin Ọlọrun nítorí àánú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí èyí, n óo yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo kọrin sí orúkọ rẹ.” Ó tún sọ pé, “Ẹ bá àwọn eniyan rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè.” Ó tún sọ pé, “Ẹ yin Oluwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè kí gbogbo eniyan yìn ín.” Aisaya tún sọ pé, “Gbòǹgbò kan yóo ti ìdílé Jese yọ, yóo yọ láti pàṣẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí àwọn orílẹ̀-èdè wà.” Kí Ọlọrun tí ó ń fúnni ní ìrètí fi ayọ̀ tí ò kún ati alaafia fun yín nípa igbagbọ yín, kí ẹ lè máa dàgbà ninu ìrètí tí ẹ ní ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀yin ará, ó dá mi lójú pé ẹ̀yin fúnra yín kún fún inú rere, ẹ ní ìmọ̀ ohun gbogbo, ẹ mọ irú ìmọ̀ràn tí ẹ lè máa gba ara yín. Sibẹ, mo ti fi ìgboyà tẹnumọ́ àwọn kókó ọ̀rọ̀ mélòó kan ninu ìwé yìí, láti ran yín létí nípa wọn. Mo ní ìgboyà láti sọ wọ́n fun yín nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi láti jẹ́ iranṣẹ Kristi Jesu sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Mò ń ṣe iṣẹ́ alufaa láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi nípa wiwaasu ìyìn rere Ọlọrun, kí wọ́n lè jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọrun, ọrẹ tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti yà sí mímọ́. Nítorí náà, mo ní ohun tí mo lè fi ṣògo ninu Kristi Jesu, ninu iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún Ọlọrun. N kò jẹ́ sọ nǹkankan àfi àwọn nǹkan tí Kristi tọwọ́ mi ṣe, láti mú kí àwọn tí wọn kì í ṣe Juu lè gbọ́ràn sí Ọlọrun. Mo ṣe àwọn nǹkan wọnyi nípa ọ̀rọ̀ ati ìṣe mi, pẹlu àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ẹ̀mí fún mi lágbára láti ṣe. Àyọrísí èyí ni pé láti Jerusalẹmu títí dé Iliriku ni mo ti waasu ìyìn rere Kristi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kì í ṣe àníyàn mi ni láti lọ waasu ìyìn rere níbi tí wọ́n bá ti gbọ́ orúkọ Kristi, kí n má baà kọ́lé lórí ìpìlẹ̀ tí ẹlòmíràn ti fi lélẹ̀. Ṣugbọn àníyàn mi rí bí ọ̀rọ̀ tí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Àwọn ẹni tí kò gbọ́ nípa rẹ̀ rí, yóo rí i. Ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yóo yé àwọn tí kò gbúròó rẹ̀ rí.”

Rom 15:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má sì ṣe ohun tí ó wu ara wa. Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró. Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe ohun tí ó wu ara rẹ̀, ṣùgbọ́n bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mi.” Nítorí ohun gbogbo tí a kọ tẹ́lẹ̀, ni a kọ láti fi kọ́ wa pé, nípa sùúrù àti ìtùnú ìwé mímọ́, kí àwa lè ní ìrètí. Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin láti ní inú kan sí ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jesu Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jesu Kristi. Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run. Mo sì wí pé, a rán Kristi láti ṣe ìránṣẹ́ ìkọlà àwọn tí ṣe Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀, kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrín àwọn Kèfèrí, Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.” Ó sì tún wí pé, “Ẹ̀yin Kèfèrí, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí; ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.” Isaiah sì tún wí pé, “Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá, òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí; Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.” Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, a sì fi gbogbo ìmọ̀ kún un yín, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín. Síbẹ̀ mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi Jesu láàrín àwọn Kèfèrí láti polongo ìyìnrere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àlùfáà, kí àwọn Kèfèrí lè jẹ́ ẹbọ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ yà sí mímọ́. Nítorí náà, mo ní ìṣògo nínú Kristi Jesu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run. Èmi kò sá à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò ṣe èyí tí Kristi ti ọwọ́ mi ṣe, ní títọ́ àwọn Kèfèrí ṣọ́nà láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi, nípa agbára iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìyìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìnrere Kristi ní ibi gbogbo tí wọn kò tí ì mọ̀ ọ́n, kí èmi kí ó má ṣe máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Àwọn ẹni tí a kò tí ì sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i, àti àwọn tí kò tí ì gbọ́, òye yóò sì yé.”