Rom 14:9-18
Rom 14:9-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori idi eyi na ni Kristi ṣe kú, ti o si tún yè, ki o le jẹ Oluwa ati okú ati alãye. Ṣugbọn ẽṣe ti iwọ fi nda arakunrin rẹ lẹjọ? tabi ẽsitiṣe ti iwọ fi nkẹgan arakunrin rẹ? gbogbo wa ni yio sá duro niwaju itẹ́ idajọ Kristi. Nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Bi emi ti wà, gbogbo ẽkún ni yio kunlẹ fun mi, ati gbogbo ahọn ni yio si jẹwọ fun Ọlọrun. Njẹ nitorina, olukuluku wa ni yio jihin ara rẹ̀ fun Ọlọrun. Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a tun mã da ara wa lẹjọ mọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã ṣe idajọ eyi, ki ẹnikẹni máṣe fi ohun ikọsẹ tabi ohun idugbolu si ọ̀na arakunrin rẹ̀. Mo mọ̀, o si dá mi loju ninu Jesu Oluwa pe, kò si ohun ti o ṣe aimọ́ fun ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba kà ohunkohun si aimọ́, on li o ṣe aimọ́ fun. Ṣugbọn bi inu arakunrin rẹ ba bajẹ nitori onjẹ rẹ, njẹ iwọ kò rìn ninu ifẹ mọ́. Ẹniti Kristi kú fun, máṣe fi onjẹ rẹ pa a kúgbe. Njẹ ẹ máṣe jẹ ki a mã sọ̀rọ ire nyin ni buburu. Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe jijẹ ati mimu; bikoṣe ododo, ati alafia, ati ayọ̀ ninu Ẹmí Mimọ́. Nitori ẹniti o ba nsìn Kristi ninu nkan wọnyi, li o ṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun, ti o si ni iyin lọdọ enia.
Rom 14:9-18 Yoruba Bible (YCE)
Ìdí tí Kristi fi kú nìyí, tí ó sì tún jí, kí ó lè jẹ́ Oluwa àwọn òkú ati ti àwọn alààyè. Kí ni ìdí tí o fi ń dá arakunrin rẹ lẹ́jọ́? Sọ ọ́ kí á gbọ́! Tabi kí ló dé tí ò ń fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ? Gbogbo wa mà ni a óo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun! Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Oluwa fi ara rẹ̀ búra, ó ní, ‘Èmi ni gbogbo orúnkún yóo kúnlẹ̀ fún, Èmi ni gbogbo ẹnu yóo pè ní Ọlọrun.’ ” Nítorí náà, olukuluku wa ni yóo sọ ti ẹnu ara rẹ̀ níwájú Ọlọrun. Ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ìpinnu kan tí à bá ṣe ni pé, kí á má ṣe fi ohun ìkọsẹ̀ kan, tabi ohunkohun tí yóo ṣi arakunrin wa lọ́nà, sí ojú ọ̀nà rẹ̀. Mo mọ èyí, ó sì dá mi lójú nípa àṣẹ Oluwa Jesu pé kò sí ohunkohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ ní jíjẹ fún ara rẹ̀. Ṣugbọn tí ẹnìkan bá ka nǹkan sí èèwọ̀, èèwọ̀ ni fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. Nítorí bí o bá mú ìdààmú bá arakunrin rẹ nípa ọ̀ràn oúnjẹ tí ò ń jẹ, a jẹ́ pé, kì í ṣe ìfẹ́ ni ń darí ìgbésí-ayé rẹ mọ́. Má jẹ́ kí oúnjẹ tí ò ń jẹ mú ìparun bá ẹni tí Jesu ti ìtorí rẹ̀ kú. Má ṣe fi ààyè sílẹ̀ fún ìsọkúsọ nípa àwọn ohun tí ẹ kà sí nǹkan rere. Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ọ̀ràn nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu, ọ̀ràn òdodo, alaafia ati ayọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni. Ẹni tí ó bá ń sin Kristi báyìí jẹ́ ẹni tí inú Ọlọrun dùn sí, tí àwọn eniyan sì gbà fún.
Rom 14:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìdí èyí náà ni Kristi ṣe kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààyè. Èéṣe nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èéṣe tí ìwọ fi ń gàn wọn? Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: “ ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè,’ ni Olúwa wí, ‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi; gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ” Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ má ṣe tún jẹ́ kí a máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arákùnrin tàbí arábìnrin yín. Mo mọ̀ dájú gbangba bí ẹni tí ó wà nínú Jesu Olúwa pé, kò sí ohun tó ṣe àìmọ́ fún ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ka ohunkóhun sí àìmọ́, òun ni ó ṣe àìmọ́ fún. Bí inú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí oúnjẹ rẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má ṣe fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kristi kú fún di ẹni ègbé. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ ohun tí ẹ mọ̀ sí rere ní búburú. Nítorí ìjọba ọ̀run kì í ṣe jíjẹ àti mímu, bí kò ṣe nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nítorí ẹni tí ó bá sin Kristi nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.