Rom 14:1-9

Rom 14:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ fa àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́ra, kì í ṣe láti máa bá wọn jiyàn lórí ohun tí kò tó iyàn. Ẹnìkan ní igbagbọ pé kò sí ohun tí òun kò lè jẹ, ṣugbọn ẹni tí igbagbọ rẹ̀ kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ rọra ń jẹ ẹ̀fọ́ ní tirẹ̀. Kí ẹni tí ń jẹran má fi ojú tẹmbẹlu ẹni tí kì í jẹ. Kí ẹni tí kì í jẹ má sì ṣe dá ẹni tí ó ń jẹ lẹ́bi, nítorí Ọlọrun ti gbà á. Ta ni ìwọ tí ò ń dá ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Kì báà dúró, kì báà sì ṣubú, ọ̀gá rẹ̀ nìkan ni ìdájọ́ tọ́ sí. Yóo tilẹ̀ dúró ni, nítorí Oluwa lè gbé e ró. Ẹnìkan ka ọjọ́ kan sí ọjọ́ pataki ju ọjọ́ mìíràn lọ, ẹlòmíràn ka gbogbo ọjọ́ sí bákan náà. Ẹ jẹ́ kí olukuluku pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ nípa irú ọ̀ràn báwọ̀nyí. Ẹni tí ó gbé ọjọ́ kan ga ju ọjọ́ mìíràn lọ, ti Oluwa ni ó ń rò. Ẹni tí ó ń jẹ oríṣìíríṣìí oúnjẹ, ó ń jẹ ẹ́ nítorí Oluwa. Ọpẹ́ ni ó ń fi fún Ọlọrun. Ẹni tí kò jẹ, kò jẹ ẹ́ nítorí Oluwa, ọpẹ́ ni òun náà ń fi fún Ọlọrun. Kò sí ẹni tí ó lè wà láàyè fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni, kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, òun nìkan ni ikú òun kàn. Bí a bá wà láàyè, Oluwa ni a wà láàyè fún. Bí a bá sì kú, Oluwa ni a kú fún. Nítorí náà, ààyè wa ni o, òkú wa ni o, ti Oluwa ni wá. Ìdí tí Kristi fi kú nìyí, tí ó sì tún jí, kí ó lè jẹ́ Oluwa àwọn òkú ati ti àwọn alààyè.

Rom 14:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má ṣe tọpinpin ìṣeyèméjì rẹ̀. Ẹnìkan gbàgbọ́ pé òun lè máa jẹ ohun gbogbo: ṣùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan. Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ; kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi: nítorí Ọlọ́run ti gbà á. Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun dúró, tàbí ṣubú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró. Ẹnìkan bu ọlá fún ọjọ́ kan ju òmíràn; ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀. Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, bí a wà láààyè, tàbí bí a kú, ti Olúwa ni àwa i ṣe. Nítorí ìdí èyí náà ni Kristi ṣe kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààyè.