Rom 13:1-14
Rom 13:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
KI olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti o wà ni ipo giga. Nitori kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati ọdọ Ọlọrun wá: awọn alaṣẹ ti o si wà, lati ọdọ Ọlọrun li a ti làna rẹ̀ wá. Nitorina ẹniti o ba tapá si aṣẹ, o tapá si ìlana Ọlọrun: awọn ẹniti o ba si ntapá, yio gbà ẹbi fun ara wọn. Nitori awọn ijoye kì iṣe ẹ̀ru si iṣẹ rere, bikoṣe si iṣẹ buburu. Njẹ iwọ ha fẹ ṣaibẹru aṣẹ wọn? ṣe eyi ti o dara, iwọ ó si gbà iyìn lati ọdọ rẹ̀: Nitori iranṣẹ Ọlọrun ni iṣe si ọ fun rere. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe buburu, bẹru; nitori kò gbé idà na lasan: nitori iranṣẹ Ọlọrun ni iṣe, olugbẹsan lati ṣiṣẹ ibinu lara ẹniti nṣe buburu. Nitorina ẹnyin kò gbọdọ ṣaima tẹriba, kì iṣe nitoriti ibinu nikan, ṣugbọn nitori ẹri-ọkàn pẹlu. Nitori idi eyi na li ẹ ṣe san owo-ode pẹlu: nitori iranṣẹ Ọlọrun ni nwọn eyiyi na ni nwọn mbojuto nigbagbogbo. Nitorina ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo: owo-ode fun ẹniti owo-ode iṣe tirẹ̀: owo-bode fun ẹniti owo-bode iṣe tirẹ̀; ẹ̀ru fun ẹniti ẹ̀ru iṣe tirẹ̀; ọlá fun ẹniti ọlá iṣe tirẹ̀. Ẹ máṣe jẹ ẹnikẹni ni gbese ohun kan, bikoṣepe ki a fẹran ọmọnikeji ẹni: nitori ẹniti o ba fẹran ọmọnikeji rẹ̀, o kó ofin já. Nitori eyi, Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga, Iwọ kò gbọdọ pania, Iwọ kò gbọdọ jale, Iwọ kò gbọdọ jẹri eke, Iwọ kò gbọdọ ṣojukòkoro; bi ofin miran ba si wà, a ko o pọ ninu ọ̀rọ yi pe, Fẹran ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. Ifẹ kì iṣe ohun buburu si ọmọnikeji rẹ̀: nitorina ifẹ li akója ofin. Ati eyi, bi ẹ ti mọ̀ akokò pe, o ti to wakati nisisiyi fun nyin lati ji loju orun: nitori nisisiyi ni igbala wa sunmọ etile jù igbati awa ti gbagbọ́ lọ. Oru bukọja tan, ilẹ si fẹrẹ mọ́: nitorina ẹ jẹ ki a bọ́ ara iṣẹ òkunkun silẹ, ki a si gbe ihamọra imọlẹ wọ̀. Jẹ ki a mã rìn ìrin titọ, bi li ọsán; kì iṣe ni iréde-oru ati ni imutipara, kì iṣe ni iwa-ẽri ati wọbia, kì iṣe ni ìja ati ilara. Ṣugbọn ẹ gbe Jesu Kristi Oluwa wọ̀, ki ẹ má si pèse fun ara, lati mã mu ifẹkufẹ rẹ̀ ṣẹ.
Rom 13:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo eniyan níláti fi ara wọn sí abẹ́ àwọn aláṣẹ ìlú, nítorí kò sí àṣẹ kan àfi èyí tí Ọlọrun bá lọ́wọ́ sí. Àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, Ọlọrun ni ó yàn wọ́n. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fojú di aláṣẹ ń tàpá sí àṣẹ Ọlọrun. Àwọn tí ó bá sì ṣe àfojúdi yóo forí ara wọn gba ìdájọ́. Nítorí àwọn aláṣẹ kò wà láti máa dẹ́rù ba àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn oníṣẹ́ ibi ni ó ń bẹ̀rù àwọn aláṣẹ. Ṣé o kò fẹ́ kí òfin máa já ọ láyà? Máa ṣe ohun rere, o óo sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣòfin. Nítorí iṣẹ́ Oluwa ni àwọn aṣòfin ń ṣe fún rere rẹ. Ṣugbọn bí o bá ń ṣe nǹkan burúkú, o jẹ́ bẹ̀rù! Nítorí kì í ṣe lásán ni idà tí ó wà lọ́wọ́ wọn. Ọlọrun ni ó gbà wọ́n sí iṣẹ́ láti fi ibinu gbẹ̀san lára àwọn tí ó bá ń ṣe nǹkan burúkú. Nítorí náà, eniyan níláti foríbalẹ̀, kì í ṣe nítorí ẹ̀rù ibinu Ọlọrun nìkan, ṣugbọn nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wa pàápàá sọ fún wa pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ìdí kan náà nìyí tí ẹ fi ń san owó-orí. Iṣẹ́ Ọlọrun ni àwọn aláṣẹ ń ṣe, nǹkankan náà tí wọ́n tẹra mọ́ nìyí. Nítorí náà, ẹ san ohun tí ẹ bá jẹ ẹnikẹ́ni pada fún un. Ẹ san owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí. Ẹ san owó-odè fún ẹni tí owó-odè yẹ. Ẹ bu ọlá fún ẹni tí ọlá bá yẹ. Ẹ má jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ohunkohun, àfi gbèsè ìfẹ́ tí ẹ jẹ ara yín. Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹnìkejì ti pa gbogbo òfin mọ́. “Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ” ni kókó òfin bíi, “Má ṣe àgbèrè, má jalè, má ṣe ojúkòkòrò,” ati èyíkéyìí tí ó kù ninu òfin. Ìfẹ́ kò jẹ́ ṣe nǹkan burúkú sí ẹnìkejì. Nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin. Ó yẹ kí ẹ mọ irú àkókò tí a wà yìí, kí ẹ tají lójú oorun. Nítorí àkókò ìgbàlà wa súnmọ́ tòsí ju ìgbà tí a kọ́kọ́ gbàgbọ́ lọ. Alẹ́ ti lẹ́ tipẹ́. Ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa iṣẹ́ òkùnkùn tì, kí á múra gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun ìmọ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á máa rìn bí ó ti yẹ ní ọ̀sán, kí á má wà ninu àwùjọ aláriwo ati ọ̀mùtí, kí á má máa ṣe ìṣekúṣe, kí á má máa hu ìwà wọ̀bìà, kí á má máa ṣe aáwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí á má máa jowú. Ṣugbọn ẹ gbé Oluwa Jesu Kristi wọ̀ bí ihamọra. Ẹ má jẹ́ kí á máa gbèrò láti ṣe àwọn ohun tí ara fẹ́.
Rom 13:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti lànà rẹ̀ wá. Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run; àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn. Nítorí àwọn ìjòyè kò wá láti dẹ́rùbà àwọn tí ń ṣe rere, bí kò ṣe àwọn tó ń ṣe búburú. Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ di òmìnira kúrò nínú ẹ̀rù ẹni tó wà ní ipò àṣẹ. Nítorí náà ṣe èyí tó ó dára, ìwọ yóò sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni i ṣe fún ọ́ sí rere. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣé búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kò gbé idà náà lásán. Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní í ṣe, olùgbẹ̀san láti ṣiṣẹ́ ìbínú lára ẹni tí ń ṣe búburú. Nítorí náà, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ má tẹríba fún àwọn aláṣẹ, kì í ṣe nítorí ti ìbínú nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí ọkàn pẹ̀lú. Nítorí ìdí èyí, ẹ san owó òde pẹ̀lú, nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n, èyí náà ni wọ́n ń bojútó nígbà gbogbo. Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó òde fún ẹni tí owó òde í ṣe tirẹ̀: owó bodè fún ẹni tí owó bodè í ṣe tirẹ̀: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù í ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá í ṣe tirẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ni nígbésè ohun kan, bí kò ṣe pé kí a fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já. Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ ṣọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ẹnìkéjì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.” Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀: nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin. Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ. Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara. Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.