Rom 12:1-8

Rom 12:1-8 Yoruba Bible (YCE)

Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ̀yin ará, mo fỌlọrun aláàánú bẹ̀ yín pé kí ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ bí ẹbọ mímọ́ tí ó yẹ láti fi sin Ọlọrun. Èyí ni iṣẹ́ ìsìn tí ó yẹ yín. Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ẹ para dà, kí ọkàn yín di titun, kí ẹ lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé. Nítorí nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi, mò ń sọ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láàrin yín pé kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ jù bí ó ti yẹ lọ. Ṣugbọn kí olukuluku ronú níwọ̀n, kí ó máa ṣe jẹ́jẹ́, níwọ̀nba bí Ọlọrun ti pín ẹ̀bùn igbagbọ fún un. Nítorí bí a ti ní ẹ̀yà ara pupọ ninu ara kan, tí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara wọnyi kì í sìí ṣe iṣẹ́ kan náà, bẹ́ẹ̀ gan-an ni gbogbo wa, bí á tilẹ̀ pọ̀, ara kan ni wá ninu Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa sì jẹ́ ẹ̀yà ara ẹnìkejì rẹ̀. Bí a ti ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pín oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí á lò wọ́n. Bí ẹnìkan bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, kí ó lò ó gẹ́gẹ́ bí igbagbọ rẹ̀ ti mọ. Bí ó bá jẹ́ ẹ̀bùn láti darí ètò ni, kí á lò ó láti darí ètò. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn ìkọ́ni, kí ó lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Bí ó bá ní ẹ̀bùn láti fúnni ní ọ̀rọ̀ ìwúrí, kí ó lò ó láti lé ìrẹ̀wẹ̀sì jìnnà. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, kí ó ṣe é pẹlu ọkàn kan. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn láti ṣe aṣiwaju, kí ó ṣe é tọkàntọkàn. Ẹni tí ó bá ń ṣiṣẹ́ àánú, kí ó fọ̀yàyà ṣe é.

Rom 12:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà. Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di tuntun ní èrò inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé. Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ́ntún-wọ́nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olúkúlùkù. Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà púpọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà: Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ púpọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kristi, àti olúkúlùkù ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀. Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; Tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é.

Rom 12:1-8

Rom 12:1-8 YBCVRom 12:1-8 YBCVRom 12:1-8 YBCVRom 12:1-8 YBCVRom 12:1-8 YBCVRom 12:1-8 YBCV