Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Rom 11:17YBCV(Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi a ba yà ninu awọn ẹ̀ka kuro, ti a si lọ́ iwọ, ti iṣe igi oróro igbẹ́ sara wọn, ti iwọ si mba wọn pín ninu gbòngbo ati ọra igi oróro na
Rom 11:17BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí a bá ya nínú àwọn ẹ̀ka kúrò, tí a sì lọ́ ìwọ, tí í ṣe igi òróró igbó sára wọn, tí ìwọ sì ń bá wọn pín nínú gbòǹgbò àti ọ̀rá igi olifi náà
Rom 11:17YCE(Yoruba Bible)
A gé díẹ̀ ninu àwọn ẹ̀ka igi olifi inú oko kúrò, a wá lọ́ ẹ̀ka igi olifi inú tí ó lalẹ̀ hù ninu ìgbẹ́ dípò rẹ̀. Ẹ̀yin, tí ẹ kì í ṣe Juu, wá dàbí ẹ̀ka igi olifi tí ó lalẹ̀ hù ninu ìgbẹ́. Ẹ wá jọ ń rí oúnjẹ ati agbára láti ibìkan náà pẹlu àwọn Juu, tí ó jẹ́ igi olifi inú oko.