Rom 11:11-16
Rom 11:11-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ mo ni, Nwọn ha kọsẹ̀ ki nwọn ki o le ṣubu? Ki a má ri: ṣugbọn nipa iṣubu wọn, igbala dé ọdọ awọn Keferi, lati mu wọn jowú. Ṣugbọn bi iṣubu wọn ba di ọrọ̀ aiye, ati bi ifasẹhin wọn ba di ọrọ̀ awọn Keferi; melomelo ni kíkún wọn? Ẹnyin ti iṣe Keferi li emi sa mba sọrọ, niwọnbi emi ti jẹ aposteli awọn Keferi, mo gbé oyè mi ga: Bi o le ṣe ki emi ki o le mu awọn ará mi jowú, ati ki emi ki o le gbà diẹ là ninu wọn. Nitori bi titanù wọn ba jẹ ìlaja aiye, gbigbà wọn yio ha ti ri, bikoṣe iyè kuro ninu okú? Njẹ bi akọso ba mọ́, bẹ̃li akopọ: bi gbòngbo ba si mọ́, bẹ si li awọn ẹ̀ka rẹ̀ na.
Rom 11:11-16 Yoruba Bible (YCE)
Mo tún bèèrè: ǹjẹ́ nígbà tí àwọn Juu kọsẹ̀, ṣé wọ́n ṣubú gbé ni? Rárá o! Ṣugbọn nítorí ìṣìnà wọn ni ìgbàlà fi dé ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí àwọn Juu baà lè máa jowú. Ǹjẹ́ bí ìṣìnà wọn bá ṣe ayé ní anfaani, bí ìkùnà wọn bá ṣe orílẹ̀-èdè yòókù ní anfaani, báwo ni anfaani náà yóo ti pọ̀ tó nígbà tí gbogbo wọn bá ṣe ojúṣe wọn? Ẹ̀yin ará, tí ẹ kì í ṣe Juu ni mò ń bá sọ̀rọ̀ nisinsinyii. Níwọ̀n ìgbà tí mo jẹ́ Aposteli láàrin yín, mò ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ mi, pé bóyá mo lè ti ipa bẹ́ẹ̀ mú àwọn eniyan mi jowú yín, kí n lè gba díẹ̀ ninu wọn là. Nítorí bí kíkọ̀ tí Ọlọrun kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bá mú kí aráyé bá Ọlọrun rẹ́, kí ni yóo ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbà wọ́n mọ́ra? Ǹjẹ́ òkú pàápàá kò ní jí dìde? Bí a bá ya ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ rí ninu ìkórè sí mímọ́, a ti ya burẹdi tí a fi ṣe sí mímọ́. Bí a bá ya gbòǹgbò igi sí mímọ́, a ti ya àwọn ẹ̀ka igi náà sí mímọ́.
Rom 11:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ mo ní, wọ́n ha kọsẹ̀ kí wọn kí ó lè ṣubú? Kí a má ri i, ṣùgbọ́n nípa ìṣubú wọn, ìgbàlà dé ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, láti mú Israẹli jowú. Ṣùgbọ́n bí ìṣubú wọn bá di ọrọ̀ ayé, àti bí ìfàsẹ́yìn wọn bá di ọrọ̀ àwọn Kèfèrí; mélòó mélòó ni kíkún ọrọ̀ wọn? Ẹ̀yin tí i ṣe Kèfèrí ni èmi sá à ń bá sọ̀rọ̀, níwọ̀n bí èmi ti jẹ́ aposteli àwọn Kèfèrí, mo gbé oyè mi ga bí ó le ṣe kí èmi kí ó lè mú àwọn ará mi jowú, àti kí èmi kí ó lè gba díẹ̀ là nínú wọn. Nítorí bí títanù wọn bá jẹ́ ìlàjà ayé, gbígbà wọn yóò ha ti rí, bí kò sí ìyè kúrò nínú òkú? Ǹjẹ́ bí àkọ́so bá jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni àkópọ̀ yóò jẹ́ mímọ́; bí gbòǹgbò bá sì jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀ka rẹ̀ náà.