Rom 10:1-21

Rom 10:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

ARÁ, ifẹ ọkàn mi ati adura mi si Ọlọrun fun Israeli ni, fun igbala wọn. Nitori mo gbà ẹri wọn jẹ pe, nwọn ni itara fun Ọlọrun, ṣugbọn kì iṣe gẹgẹ bi ìmọ. Nitori bi nwọn kò ti mọ ododo Ọlọrun, ti nwọn si nwá ọna lati gbé ododo ara wọn kalẹ, nwọn kò tẹriba fun ododo Ọlọrun. Nitori Kristi li opin ofin si ododo fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́. Mose sá kọ̀we rẹ̀ pe, ẹniti o ba ṣe ododo ti iṣe ti ofin, yio yè nipa rẹ̀. Ṣugbọn ododo ti iṣe ti igbagbọ́ sọ bayi pe, Máṣe wi li ọkàn rẹ pe, tani yio goke lọ si ọrun? (eyini ni, lati mu Kristi sọkalẹ:) Tabi, tani yio sọkalẹ lọ si ọgbun? (eyini ni, lati mu Kristi goke ti inu okú wá). Ṣugbọn kili o wi? Ọ̀rọ na wà leti ọdọ rẹ, li ẹnu rẹ, ati li ọkan rẹ: eyini ni, ọ̀rọ igbagbọ́, ti awa nwasu; Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là. Nitori ọkàn li a fi igbagbọ́ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala. Nitori iwe-mimọ́ wipe, Ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ oju ki yio ti i. Nitori kò si ìyatọ ninu Ju ati Hellene: nitori Oluwa kanna l'Oluwa gbogbo wọn, o si pọ̀ li ọrọ̀ fun gbogbo awọn ti nkepè e. Nitori ẹnikẹni ti o ba sá pè orukọ, Oluwa, li a o gbàlà. Njẹ nwọn o ha ti ṣe kepe ẹniti nwọn kò gbagbọ́? nwọn o ha si ti ṣe gbà ẹniti nwọn kò gburó rẹ̀ rí gbọ́? nwọn o ha si ti ṣe gbọ́ laisi oniwasu? Nwọn o ha si ti ṣe wasu, bikoṣepe a rán wọn? gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹsẹ awọn ti nwasu ihinrere alafia ti dara to, awọn ti nwãsu ihin ayọ̀ ohun rere! Ṣugbọn ki iṣe gbogbo wọn li o gbọ́ ti ihinrere. Nitori Isaiah wipe, Oluwa, tali o gbà ihin wa gbọ́? Njẹ nipa gbigbọ ni igbagbọ́ ti iwá, ati gbigbọ nipa ọ̀rọ Ọlọrun. Ṣugbọn mo ni, Nwọn kò ha gbọ́ bi? Bẹni nitõtọ, Ohùn wọn jade lọ si gbogbo ilẹ, ati ọ̀rọ wọn si opin ilẹ aiye. Ṣugbọn mo ni, Israeli kò ha mọ̀ bi? Mose li o kọ́ wipe, Emi o fi awọn ti kì iṣe enia mu nyin jowú, ati awọn alaimoye enia li emi o fi bi nyin ninu. Ṣugbọn Isaiah tilẹ laiya, o si wipe, Awọn ti kò wá mi ri mi; awọn ti kò bère mi li a fi mi hàn fun. Ṣugbọn nipa ti Israeli li o wipe, Ni gbogbo ọjọ ni mo nà ọwọ́ mi si awọn alaigbọran ati alariwisi enia.

Rom 10:1-21 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ará mi, ìfẹ́ ọkàn mi, ati ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọrun fún àwọn Juu, àwọn eniyan mi ni pé kí á gbà wọ́n là. Nítorí mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara láti sin Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò ní òye bí ó ti yẹ kí wọ́n sìn ín. Wọn kò tíì ní òye ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dáni láre, nítorí náà wọ́n wá ọ̀nà ti ara wọn, wọn kò sì fi ara wọn sábẹ́ ètò tí Ọlọrun ṣe fún ìdániláre. Nítorí Kristi ti fi òpin sí Òfin láti mú gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ rí ìdáláre níwájú Ọlọrun. Mose kọ sílẹ̀ báyìí nípa ìdáláre tí Òfin lè fúnni pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa wọ́n mọ́, yóo ti ipa wọn rí ìyè.” Ṣugbọn báyìí ni Ìwé Mímọ́ wí nípa ìdáláre tí à ń gbà nípa igbagbọ, pé, “Má ṣe wí ní ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóo gòkè lọ sọ́run?’ ” (Èyí ni láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀.) “Tabi, ‘Ta ni yóo wọ inú ọ̀gbun ilẹ̀ lọ?’ ” (Èyí ni, láti mú Kristi jáde kúrò láàrin àwọn òkú.) Ṣugbọn ohun tí ó sọ ni pé, “Ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ, àní, ó wà lẹ́nu rẹ ati lọ́kàn rẹ.” Èyí ni ọ̀rọ̀ igbagbọ tí à ń waasu, pé: bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ pé, “Jesu ni Oluwa,” tí o sì gbàgbọ́ lọ́kàn rẹ pé Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú, a óo gbà ọ́ là. Nítorí pẹlu ọkàn ni a fi ń gbàgbọ́ láti rí ìdáláre gbà. Ṣugbọn ẹnu ni a fi ń jẹ́wọ́ láti rí ìgbàlà. Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ tí ojú yóo tì.” Nítorí kò sí ìyàtọ̀ kan láàrin Juu ati Giriki. Nítorí Ọlọrun kan náà ni Oluwa gbogbo wọn, ọlá rẹ̀ sì pọ̀ tó fún gbogbo àwọn tí ó bá ń ké pè é. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” Ṣugbọn báwo ni wọn yóo ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Báwo ni wọn yóo ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ gbọ́? Báwo ni wọn yóo ṣe gbúròó rẹ̀ láìsí àwọn tí ó ń kéde rẹ̀? Báwo ni àwọn kan yóo ṣe lọ kéde rẹ̀ láìjẹ́ pé a bá rán wọn lọ? Ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Àwọn tí ó mú ìyìn rere wá mà mọ̀ ọ́n rìn o!” Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gba ìyìn rere yìí gbọ́. Aisaya ṣá sọ ọ́ pé, “Oluwa, ta ni ó gba ohun tí a sọ gbọ́?” Ṣebí ohun tí a bá gbọ́ ni à ń gbàgbọ́, ohun tí a sì gbọ́ yìí ni ọ̀rọ̀ Kristi? Mo wá ń bèèrè, “Ṣé wọn kò ì tíì gbọ́ ni?” Wọ́n kúkú ti gbọ́, nítorí a rí i kà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Ìró wọn ti dé gbogbo orílẹ̀-èdè, àní, ọ̀rọ̀ wọn ti dé òpin ayé.” Mo tún bèèrè: Àbí Israẹli kò mọ̀ ni? Ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ohun tí Mose kọ́kọ́ sọ; ó ní, “N óo jẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe orílẹ̀-èdè mu yín jowú, N óo sì jẹ́ kí orílẹ̀-èdè tí kò lóye mú kí ara ta yín.” Aisaya pàápàá kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ kọ́ òun lẹ́nu, ó ní, “Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi, àwọn tí kò bèèrè mi ni mo fi ara hàn fún.” Ṣugbọn ohun tí ó ní Ọlọrun wí fún Israẹli ni pé, “Láti òwúrọ̀ títí di alẹ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọràn ati alágídí eniyan.”

Rom 10:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi sí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Israẹli ni kí wọ́n le ní ìgbàlà. Nítorí mo gba ẹ̀rí wọn jẹ́ wí pé, wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀. Nítorí bí wọn kò tí mọ òdodo Ọlọ́run, tí wọ́n si ń wá ọ̀nà láti gbé òdodo ara wọn kalẹ̀, wọn kò tẹríba fún òdodo Ọlọ́run. Nítorí Kristi ni òpin òfin sí òdodo fún olúkúlùkù ẹni tí ó gbà á gbọ́. Mose ṣá kọ èyí nípa òdodo tí í ṣe ti òfin pé, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” Ṣùgbọ́n òdodo tí í ṣe ìgbàgbọ́ wí pé, “Má ṣe wí ni ọkàn rẹ̀ pé, ta ni yóò gòkè lọ si ọ̀run?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀) “tàbí, ta ni yóò sọ̀kalẹ̀ lọ si ọ̀gbun?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi gòkè ti inú òkú wá). Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà létí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ẹnu rẹ̀, àti ní ọkàn rẹ̀,” èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, tí àwa ń wàásù; Pé, bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là. Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà. Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.” Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.” Ǹjẹ́ wọn ó ha ti ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o ha sì ti ṣe gbọ́ láìsí oníwàásù? Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìhìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!” Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìhìnrere. Nítorí Isaiah wí pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìyìn wa gbọ́?” Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́: “Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀, àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ilẹ̀ ayé.” Ṣùgbọ́n mo wí pé, Israẹli kò ha mọ̀ bí? Mose ni ó kọ́ wí pé, “Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú. Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.” Ṣùgbọ́n Isaiah tilẹ̀ láyà, ó wí pé, “Àwọn tí kò wá mi rí mi; Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún.” Ṣùgbọ́n nípa ti Israẹli ni ó wí pé, “Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn.”