Rom 1:8-10
Rom 1:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo kọ́ dupẹ na lọwọ Ọlọrun mi nipasẹ Jesu Kristi nitori gbogbo nyin, nitoripe a nròhin igbagbọ́ nyin yi gbogbo aiye ká. Ọlọrun sá li ẹlẹri mi, ẹniti emi nfi ẹmi mi sìn ninu ihinrere Ọmọ rẹ̀, biotiṣepe li aisimi li emi nranti nyin nigbagbogbo ninu adura mi; Emi mbẹ̀bẹ, bi lọna-kọna leke gbogbo rẹ̀, ki a le ṣe ọ̀na mi ni ire nipa ifẹ Ọlọrun, lati tọ̀ nyin wá.
Rom 1:8-10 Yoruba Bible (YCE)
Kí á tó máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nípasẹ̀ Jesu Kristi nítorí gbogbo yín; nítorí àwọn eniyan ń ròyìn igbagbọ yín ní gbogbo ayé. Ọlọrun, tí mò ń fọkàn sìn bí mo ti ń waasu ìyìn rere Ọmọ rẹ̀, ni ẹlẹ́rìí mi pé mò ń ranti yín láì sinmi. Mo sì ń bẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo ninu adura mi pé, ó pẹ́ ni, ó yá ni, kí n rí ààyè láti wá sọ́dọ̀ yín, bí Ọlọrun bá fẹ́.
Rom 1:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé. Ọlọ́run ṣá à ni ẹlẹ́rìí mi, ẹni tí èmí ń fi gbogbo ẹ̀mí mi sìn nínú ìhìnrere Ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsimi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi nínú àdúrà mi ìgbà gbogbo; mo tún ń gbàdúrà wí pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí ọ̀nà ó ṣí fún mi láti wá sọ́dọ̀ yín.