Rom 1:26-27
Rom 1:26-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori eyiyi li Ọlọrun ṣe fi wọn fun ifẹ iwakiwa: nitori awọn obinrin wọn tilẹ yi ilo ẹda pada si eyi ti o lodi si ẹda: Gẹgẹ bẹ̃ li awọn ọkunrin pẹlu, nwọn a mã fi ilò obinrin nipa ti ẹda silẹ, nwọn a mã ni ifẹkufẹ gbigbona si ara wọn; ọkunrin mba ọkunrin ṣe eyi ti kò yẹ, nwọn si njẹ ère ìṣina wọn ninu ara wọn bi o ti yẹ si.
Rom 1:26-27 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí ó ti eniyan lójú. Àwọn obinrin wọn ń bá ara wọn ṣe ohun tí kò bójú mu. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọkunrin wọn. Dípò tí ọkunrin ìbá máa fi bá obinrin lòpọ̀, ọkunrin ati ọkunrin ni wọ́n ń dìde sí ara wọn ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn. Ọkunrin ń bá ọkunrin ṣe ohun ìtìjú, wọ́n wá ń jèrè ìṣekúṣe wọn.
Rom 1:26-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.