Rom 1:16-22
Rom 1:16-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu. Nitori ninu rẹ̀ li ododo Ọlọrun hàn lati igbagbọ́ de igbagbọ́: gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ṣugbọn olododo yio wà nipa igbagbọ́. Nitori a fi ibinu Ọlọrun hàn lati ọrun wá si gbogbo aiwa-bi-Ọlọrun ati aiṣododo enia, awọn ẹniti o fi aiṣododo tẹ otitọ mọ́lẹ̀: Nitori ohun ti ã le mọ̀ niti Ọlọrun o farahàn ninu wọn; nitori Ọlọrun ti fi i hàn fun wọn. Nitori ohun rẹ̀ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi òye ohun ti a da mọ̀ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi: Nitori igbati nwọn mọ̀ Ọlọrun, nwọn kò yìn i logo bi Ọlọrun, bẹ̃ni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn èro ọkàn wọn di asán, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣókunkun. Nwọn npè ara wọn li ọlọ́gbọn, nwọn di aṣiwere
Rom 1:16-22 Yoruba Bible (YCE)
Ojú kò tì mí láti waasu ìyìn rere Jesu, nítorí ìyìn rere yìí ni agbára Ọlọrun, tí a fi ń gba gbogbo àwọn tí ó bá gbà á gbọ́ là. Ó kọ́kọ́ lo agbára yìí láàrin àwọn Juu, lẹ́yìn náà ó lò ó láàrin àwọn Giriki. Ninu ìyìn rere yìí ni a ti ń fi ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre hàn wá: nípa igbagbọ ni, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí igbagbọ ni ẹni tí a bá dá láre yóo fi yè.” Ojú ọ̀run ti ṣí sílẹ̀, Ọlọrun sì ń tú ibinu rẹ̀ sórí gbogbo eniyan nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú tí wọn ń hù, tí wọ́n fi ń ṣe ìdènà fún òtítọ́. Nítorí ohun tí eniyan lè mọ̀ nípa Ọlọrun ti hàn sí wọn, Ọlọrun ni ó ti fihàn wọ́n. Láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ayé ni ìwà ati ìṣe Ọlọrun, tí a kò lè fi ojú rí ati agbára ayérayé rẹ̀, ti hàn gedegbe ninu àwọn ohun tí ó dá. Nítorí èyí, irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kò ní àwáwí. Wọ́n mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò júbà rẹ̀ bí Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo èrò wọn di asán, òye ọkàn wọn sì ṣókùnkùn. Wọ́n ń ṣe bí ẹni pé wọ́n gbọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ya òmùgọ̀.
Rom 1:16-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi kò tijú ìhìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú. Nítorí nínú ìhìnrere ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn, òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí. Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá