Rom 1:13-16
Rom 1:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ará, emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀ pe, nigba-pupọ li emi npinnu rẹ̀ lati tọ̀ nyin wá (ṣugbọn o di ẹtì fun mi di isisiyi,) ki emi ki o le ni eso diẹ ninu nyin pẹlu, gẹgẹ bi lãrin awọn Keferi iyokù. Mo di ajigbese awọn Hellene ati awọn alaigbede; awọn ọlọ́gbọn ati awọn alaigbọn. Tobẹ̃ bi o ti wà ni ipá mi, mo mura tan lati wasu ihinrere fun ẹnyin ara Romu pẹlu. Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu.
Rom 1:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Kò yẹ kí ẹ má mọ̀, ará, pé ní ìgbà pupọ ni mo ti fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, kí n lè ní èso láàrin yín bí mo ti ní láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, ṣugbọn nǹkankan ti ń dí mi lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ títí di àkókò yìí. Nítorí pé ati àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n, ati àwọn kògbédè tí kò mọ nǹkan, gbogbo wọn ni mo jẹ ní gbèsè. Ìdí rẹ̀ nìyí tí mo ṣe ń dàníyàn láti waasu ìyìn rere fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Romu náà. Ojú kò tì mí láti waasu ìyìn rere Jesu, nítorí ìyìn rere yìí ni agbára Ọlọrun, tí a fi ń gba gbogbo àwọn tí ó bá gbà á gbọ́ là. Ó kọ́kọ́ lo agbára yìí láàrin àwọn Juu, lẹ́yìn náà ó lò ó láàrin àwọn Giriki.
Rom 1:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá, (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrín yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní láàrín àwọn aláìkọlà yòókù. Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Giriki àti sí àwọn aláìgbédè tí kì í ṣe Giriki, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aṣiwèrè. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Romu àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìhìnrere Ọlọ́run sí i yín. Èmi kò tijú ìhìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú.