Ifi 6:1-17

Ifi 6:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

EMI si ri nigbati Ọdọ-Agutan na ṣí ọ̀kan ninu èdidi wọnni, mo si gbọ́ ọ̀kan ninu awọn ẹda alãye mẹrin nì nwi bi ẹnipe sisan ãrá pe, Wá, wò o. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin funfun kan: ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni ọrun kan; a si fi ade kan fun u: o si jade lọ lati iṣẹgun de iṣẹgun. Nigbati o si ṣí èdidi keji, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye keji nwipe, Wá, wò o. Ẹṣin miran ti o pupa si jade: a si fi agbara fun ẹniti o joko lori rẹ̀, lati gbà alafia kuro lori ilẹ aiye, ati pe ki nwọn ki o mã pa ara wọn: a si fi idà nla kan le e lọwọ. Nigbati o si ṣí èdidi kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹta nwipe, Wá, wò o. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin dúdu kan; ẹniti o joko lori rẹ̀ ni oṣuwọn awẹ́ meji li ọwọ́ rẹ̀. Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn kan li arin awọn ẹda alãye mẹrẹrin nì ti nwipe, Oṣuwọn alikama kan fun owo idẹ kan, ati oṣuwọn ọkà barle mẹta fun owo idẹ kan; si kiyesi i, ki o má si ṣe pa oróro ati ọti-waini lara. Nigbati o si ṣí èdidi kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹrin nwipe, Wá wò o. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin rọndọnrọndọn kan: orukọ ẹniti o joko lori rẹ̀ ni Ikú, ati Ipò-okú si tọ̀ ọ lẹhin. A si fi agbara fun wọn lori idamẹrin aiye, lati fi idà, ati ebi, ati ikú, ati ẹranko ori ilẹ aiye pa. Nigbati o si ṣí èdidi karun, mo ri labẹ pẹpẹ, ọkàn awọn ti a ti pa nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí ti nwọn dìmu: Nwọn kigbe li ohùn rara, wipe, Yio ti pẹ to, Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ati olõtọ, iwọ ki yio ṣe idajọ ki o si gbẹsan ẹ̀jẹ wa mọ́ lara awọn ti ngbé ori ilẹ aiye? A si fi aṣọ funfun fun gbogbo wọn; a si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o simi di ìgba diẹ na, titi iye awọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ ati arakunrin wọn ti a o pa bi wọn, yio fi pé. Nigbati o si ṣí èdidi kẹfa mo si ri, si kiyesi i, ìṣẹlẹ nla kan ṣẹ̀; õrùn si dudu bi aṣọ-ọfọ onirun, oṣupa si dabi ẹ̀jẹ; Awọn irawọ oju ọrun si ṣubu silẹ gẹgẹ bi igi ọpọtọ iti rẹ̀ àigbó eso rẹ̀ dànu, nigbati ẹfũfu nla ba mì i. A si ká ọ̀run kuro bi iwe ti a ká; ati olukuluku oke ati erekuṣu li a si ṣí kuro ni ipò wọn. Awọn ọba aiye ati awọn ọlọlá ati awọn olori ogun, ati awọn ọlọrọ̀ ati awọn alagbara, ati olukuluku ẹrú, ati olukuluku omnira, si fi ara wọn pamọ́ ninu ihò-ilẹ, ati ninu àpata ori òke: Nwọn si nwi fun awọn òke ati awọn àpata na pe, Ẹ wólu wa, ki ẹ si fi wa pamọ́ kuro loju ẹniti o joko lori itẹ́, ati kuro ninu ibinu Ọdọ-Agutan na: Nitori ọjọ nla ibinu wọn de; tani si le duro?

Ifi 6:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà nígbà tí ó ń tú ọ̀kan ninu àwọn èdìdì meje náà. Mo gbọ́ tí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin wí pẹlu ohùn tí ó dàbí ààrá, pé, “Wá!” Mo bá rí ẹṣin funfun kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ọrun ati ọfà lọ́wọ́. A fún un ní adé kan, ó bá jáde lọ bí aṣẹ́gun, ó ń ṣẹgun bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó tú èdìdì keji, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè keji ní, “Wá!” Ni ẹṣin mìíràn bá yọ jáde, òun pupa. A fi agbára fún ẹni tí ó gùn ún láti mú alaafia kúrò ní ayé, kí àwọn eniyan máa pa ara wọn. A wá fún un ní idà kan tí ó tóbi. Nígbà tí ó tú èdìdì kẹta, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹta ní, “Wá!” Mo rí ẹṣin dúdú kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Mo wá gbọ́ nǹkankan tí ó dàbí ohùn láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà, ó ní, “Páànù ọkà bàbà kan fún owó fadaka kan. Páànù ọkà baali mẹta fún owó fadaka kan. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan igi olifi ati ọtí waini.” Nígbà tí ó tú èdìdì kẹrin, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹrin ní, “Wá!” Mo wá rí ẹṣin kan tí àwọ̀ rẹ̀ rí bíi ti ewéko tútù. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Ikú. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ipò-òkú. A fún wọn ní àṣẹ láti fi idà ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ati ẹranko burúkú pa idamẹrin ayé. Nígbà tí ó tú èdìdì karun-un, ní abẹ́ pẹpẹ ìrúbọ, mo rí ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́. Àwọn náà kígbe pé, “Oluwa mímọ́ ati olóòótọ́, nígbà wo ni ìwọ yóo ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí ìwọ yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára wọn?” A wá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ funfun. A sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi díẹ̀ sí i títí iye àwọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ wọn ati àwọn arakunrin wọn yóo fi pé, àwọn tí wọn yóo pa láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pa àwọn ti iṣaaju. Mo rí i nígbà tí ó tú èdìdì kẹfa pé ilẹ̀ mì tìtì. Oòrùn ṣókùnkùn, ó dàbí aṣọ dúdú. Òṣùpá wá dàbí ẹ̀jẹ̀. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run já bọ́ sílẹ̀, bí ìgbà tí èso ọ̀pọ̀tọ́ bá já bọ́ lára igi rẹ̀ nígbà tí afẹ́fẹ́ líle bá fẹ́ lù ú. Ojú ọ̀run fẹ́ lọ bí ìgbà tí eniyan bá ká ẹní. Gbogbo òkè ati erékùṣù ni wọ́n kúrò ní ipò wọn. Àwọn ọba ayé, àwọn ọlọ́lá, àwọn ọ̀gágun, àwọn olówó, àwọn alágbára, ati gbogbo eniyan: ẹrú ati òmìnira, gbogbo wọn lọ sápamọ́ sinu ihò òkúta ati abẹ́ àpáta lára àwọn òkè. Wọ́n ń sọ fún àwọn òkè ati àpáta pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ pa wá mọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati ibinu Ọ̀dọ́ Aguntan. Nítorí ọjọ́ ńlá ibinu wọn dé; kò sì sí ẹni tí ó lè dúró.”

Ifi 6:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-àgùntàn náà ṣí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, “Wá, wò ó!” Mo sì wò ó, kíyèsi i, ẹṣin funfun kan: ẹni tí ó sì jókòó lórí i rẹ̀ ní ọfà kan; a sì fi adé kan fún un: ó sì jáde lọ láti ìṣẹ́gun dé ìṣẹ́gun. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, “Wá, wò ó!” Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde: a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn: A sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́. Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, “Wá wò ó”. Mo sì wò ó, sì kíyèsi i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ní ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òṣùwọ̀n alikama kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsi i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, Wá wò ó. Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹṣin ràndànràndàn kan: orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. A sì fi agbára fún wọn lórí ìdámẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú: Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Olódùmarè, ẹni mímọ́ àti olóòtítọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?” A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí a o pa bí wọn, yóò fi dé. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀; àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í. A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùṣù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn. Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè; Wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà: Nítorí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn dé; ta ni sì le dúró?”