Ifi 4:2-6
Ifi 4:2-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lojukanna mo si wà ninu Ẹmí: si kiyesi i, a tẹ́ itẹ́ kan li ọrun, ẹnikan si joko lori itẹ́ na. Ẹniti o si joko na dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo: oṣumare si ta yi itẹ́ na ká, o dabi okuta smaragdu ni wiwo. Yi itẹ́ na ká si ni itẹ́ mẹrinlelogun: ati lori awọn itẹ́ na mo ri awọn àgba mẹrinlelogun joko, ti a wọ̀ li aṣọ àlà; ade wura si wà li ori wọn. Ati lati ibi itẹ́ na ni mànamána ati ãrá ati ohùn ti jade wá: fitila iná meje si ntàn nibẹ̀ niwaju itẹ́ na, ti iṣe Ẹmi meje ti Ọlọrun. Ati niwaju itẹ́ na si ni okun bi digí, o dabi kristali: li arin itẹ́ na, ati yi itẹ́ na ká, li ẹda alãye mẹrin ti o kún fun oju niwaju ati lẹhin.
Ifi 4:2-6 Yoruba Bible (YCE)
Lẹsẹkẹsẹ ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo bá rí ìtẹ́ kan ní ọ̀run. Ẹnìkan jókòó lórí rẹ̀. Ojú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà dàbí òkúta iyebíye oríṣìí meji. Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, ó ń tan ìmọ́lẹ̀ bí òkúta iyebíye. Àwọn ìtẹ́ mẹrinlelogun ni wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì jókòó lórí ìtẹ́ mẹrinlelogun náà. Wọ́n wọ aṣọ funfun, wọ́n dé adé wúrà. Mànàmáná ati ìró ààrá ń jáde láti ara ìtẹ́ tí ó wà láàrin. Ògùṣọ̀ meje tí iná wọn ń jó wà níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje. Iwájú ìtẹ́ náà dàbí òkun dígí, ó rí bíi yìnyín, ó mọ́ gaara. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan wà ní ààrin, wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Wọ́n ní ọpọlọpọ ojú níwájú ati lẹ́yìn.
Ifi 4:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lójúkan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí: sì kíyèsi i, a tẹ́ ìtẹ́ kan ní ọ̀run, ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà. Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jasperi àti kaneliani lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta emeradi lójú. Yí ìtẹ́ náà ká sì ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún mìíràn; àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà; adé wúrà sì wà ni orí wọn. Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá: níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run. Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi dígí wà tí o dàbí kristali. Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn wọn.