Ifi 22:11-21

Ifi 22:11-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹniti iṣe alaiṣõtọ, ki o mã ṣe alaiṣõtọ nṣó: ati ẹniti iṣe ẹlẹgbin, ki o mã ṣe ẹlẹgbin nṣó: ati ẹniti iṣe olododo, ki o mã ṣe olododo nṣó: ati ẹniti iṣe mimọ́, ki o mã ṣe mimọ́ nṣó. Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán; ère mi si mbẹ pẹlu mi, lati san an fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀ yio ti ri. Emi ni Alfa ati Omega, ẹni iṣaju ati ẹni ikẹhin, ipilẹṣẹ̀ ati opin. Ibukún ni fun awọn ti nfọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o le ni anfani lati wá si ibi igi ìye na, ati ki nwọn ki o le gba awọn ẹnubode wọ inu ilu na. Nitori li ode ni awọn ajá gbé wà, ati awọn oṣó, ati awọn àgbere, ati awọn apania, ati awọn abọriṣa, ati olukuluku ẹniti o fẹran eke ti o si nhuwa eke. Emi Jesu li o rán angẹli mi lati jẹri nkan wọnyi fun nyin niti awọn ijọ. Emi ni gbòngbo ati iru-ọmọ Dafidi, ati irawọ owurọ̀ ti ntàn. Ati Ẹmí ati iyawo wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti o ngbọ́ ki o wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi ìye na lọfẹ. Emi njẹri fun olukuluku ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ iwe yi pe, Bi ẹnikẹni ba fi kún wọn, Ọlọrun yio fi kún awọn iyọnu ti a kọ sinu iwe yi fun u. Bi ẹnikẹni ba si mu kuro ninu ọ̀rọ iwe isọtẹlẹ yi, Ọlọrun yio si mu ipa tirẹ̀ kuro ninu iwe ìye, ati kuro ninu ilu mimọ́ nì, ati kuro ninu awọn ohun ti a kọ sinu iwe yi. Ẹniti o jẹri nkan wọnyi wipe, Nitõtọ emi mbọ̀ kánkán. Amin. Mã bọ̀, Jesu Oluwa. Ore-ọfẹ Jesu Oluwa ki o wà pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́. Amin.

Ifi 22:11-21 Yoruba Bible (YCE)

Ẹni tí ó bá ń ṣe ohun èérí, kí ó máa ṣe ohun èérí rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó bá ń hùwà rere, kí ó máa hùwà rere rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun, kí ó máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun bọ̀.” “Mò ń bọ̀ ní kíá. Èrè mi sì wà lọ́wọ́ mi, tí n óo fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí. Èmi ni Alfa ati Omega, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Àwọn tí wọ́n bá fọ aṣọ wọn ṣe oríire. Wọn óo ní àṣẹ láti dé ibi igi ìyè, wọn óo sì gba ẹnu ọ̀nà wọ inú ìlú mímọ́ náà. Lóde ni àwọn ajá yóo wà ati àwọn oṣó ati àwọn àgbèrè, ati àwọn apànìyàn ati àwọn abọ̀rìṣà ati àwọn tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe èké. “Èmi Jesu ni mo rán angẹli mi láti jíṣẹ́ gbogbo nǹkan wọnyi fún ẹ̀yin ìjọ. Èmi gan-an ni gbòǹgbò ati ọmọ Dafidi. Èmi ni ìràwọ̀ òwúrọ̀.” Ẹ̀mí ati Iyawo ń wí pé, “Máa bọ̀!” Ẹni tí ó gbọ́ níláti sọ pé, “Máa bọ̀.” Ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ kí ó wá, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. Mò ń kìlọ̀ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá fi nǹkankan kún un, Ọlọrun yóo fi kún àwọn ìyà rẹ̀ tí a ti kọ sinu ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá mú nǹkankan kúrò ninu ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí, Ọlọrun yóo mú ìpín rẹ̀ kúrò lára igi ìyè ati kúrò ninu ìlú mímọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé yìí. Ẹni tí ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, tètè máa bọ̀. Amin! Máa bọ̀, Oluwa Jesu.” Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu gbogbo yín.

Ifi 22:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì só: àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nì só: àti ẹni tí ń ṣe olódodo, kí ó máa ṣe òdodo nì só: Àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nì só.” “Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán; èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí. Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. “Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni ẹ̀tọ́ láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu ibodè wọ inú ìlú náà. Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké. “Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.” Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́. Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un. Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí. Ẹni tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí wí pé, “Nítòótọ́ èmi ń bọ̀ kánkán.” Àmín, Máa bọ̀, Jesu Olúwa! Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Àmín.