Ifi 19:1-16
Ifi 19:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN nkan wọnyi mo gbọ́ ohùn nla li ọrun bi ẹnipe ti ọ̀pọlọpọ enia, nwipe Halleluiah; ti Oluwa Ọlọrun wa ni igbala, ati ọlá agbara. Nitori otitọ ati ododo ni idajọ rẹ̀: nitori o ti ṣe idajọ àgbere nla nì, ti o fi àgbere rẹ̀ ba ilẹ aiye jẹ, o si ti gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀ lọwọ rẹ̀. Ati lẹ̃keji nwọn wipe, Halleluiah. Ẹ̃fin rẹ̀ si gòke lọ lai ati lailai. Awọn àgba mẹrinlelogun nì, ati awọn ẹda alãye mẹrin nì si wolẹ, nwọn si foribalẹ fun Ọlọrun ti o joko lori itẹ́, wipe, Amin; Halleluiah. Ohùn kan si ti ibi itẹ́ na jade wá, wipe, Ẹ mã yìn Ọlọrun wa, ẹnyin iranṣẹ rẹ̀ gbogbo, ẹnyin ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ewe ati àgba. Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn ọ̀pọlọpọ enia, ati bi iró omi pupọ̀, ati bi iró ãrá nlanla, nwipe Halleluiah: nitori Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare, njọba. Ẹ jẹ ki a yọ̀, ki inu wa ki o si dùn gidigidi, ki a si fi ogo fun u: nitoripe igbeyawo Ọdọ-Agutan de, aya rẹ̀ si ti mura tan. On ni a si fifun pe ki o wọ aṣọ ọgbọ wíwẹ ti o funfun gbõ: nitoripe aṣọ ọgbọ wíwẹ nì ni iṣẹ ododo awọn enia mimọ́. O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Ibukún ni fun awọn ti a pè si àse-alẹ igbeyawo Ọdọ-Agutan. O si wi fun mi pe, Wọnyi ni ọ̀rọ otitọ Ọlọrun. Mo si wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ lati foribalẹ fun u. O si wi fun mi pe, Wò o, máṣe bẹ̃: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ li emi, ati ti awọn arakunrin rẹ ti nwọn di ẹrí Jesu mu: foribalẹ fun Ọlọrun: nitoripe ẹrí Jesu li ẹmí isọtẹlẹ. Mo si ri ọrun ṣí silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun. Oju rẹ̀ dabi ọwọ iná, ati li ori rẹ̀ ni ade pupọ̀ wà; o si ni orukọ kan ti a kọ, ti ẹnikẹni kò mọ̀, bikoṣe on tikararẹ̀. A si wọ̀ ọ li aṣọ ti a tẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ: a si npè orukọ rẹ̀ ni Ọ̀rọ Ọlọrun. Awọn ogun ti mbẹ li ọrun ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, funfun ati mimọ́, si ntọ ọ lẹhin lori ẹṣin funfun. Ati lati ẹnu rẹ̀ ni idà mimu ti njade lọ, ki o le mã fi ṣá awọn orilẹ-ède: on o si mã fi ọpá irin ṣe akoso wọn: o si ntẹ ifúnti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare. O si ni lara aṣọ rẹ̀ ati ni itan rẹ̀ orukọ kan ti a kọ: ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA.
Ifi 19:1-16 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn èyí mo gbọ́ ohùn kan bí igbe ọ̀pọ̀ eniyan ní ọ̀run, tí ń sọ pé, “Haleluya! Ìgbàlà ati ògo ati agbára ni ti Ọlọrun wa. Òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí ó ti dájọ́ fún gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà, tí ó fi àgbèrè rẹ̀ ba ayé jẹ́. Ó ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀ lára rẹ̀.” Wọ́n tún wí lẹẹkeji pé, “Haleluya! Èéfín rẹ̀ ń gòkè lae ati laelae.” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́. Wọ́n ní, “Amin! Haleluya!” Ẹnìkan fọhùn láti orí ìtẹ́ náà, ó ní, “Ẹ yin Ọlọrun wa, gbogbo ẹ̀yin ìran rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, ẹ̀yin mẹ̀kúnnù ati ẹ̀yin eniyan pataki.” Mo tún gbọ́ ohùn kan bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, ati bí ìró ọpọlọpọ omi, ati bí sísán ààrá líle, ohùn náà sọ pé, “Haleluya! Nítorí Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare jọba. Ẹ jẹ́ kí á yọ̀, kí inú wa dùn, ẹ jẹ́ kí á fi ògo fún un, nítorí ó tó àkókò igbeyawo Ọ̀dọ́ Aguntan náà. Iyawo rẹ̀ sì ti ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ dè é. A fún un ní aṣọ funfun tí ń dán, tí ó sì mọ́. Aṣọ funfun náà ni iṣẹ́ òdodo àwọn eniyan Ọlọrun.” Ó sọ fún mi pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀: àwọn tí a pè sí àsè igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan náà ṣe oríire.” Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ọ̀rọ̀ wọnyi.” Ni mo bá dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, mo júbà rẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ bí ìwọ ati àwọn arakunrin rẹ, tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu, ni èmi náà. Ọlọrun ni kí o júbà.” Nítorí ẹ̀mí tí ó mú kí eniyan jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu ni ẹ̀mí tí ó wà ninu wolii. Mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀. Mo wá rí ẹṣin funfun kan. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Olódodo ati Olóòótọ́, nítorí pẹlu òdodo ni ó ń ṣe ìdájọ́, tí ó sì ń jagun. Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná. Ó dé adé pupọ tí a kọ orúkọ sí, orúkọ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ àfi òun alára. Ó wọ ẹ̀wù tí a rẹ sinu ẹ̀jẹ̀. Orúkọ tí à ń pè é ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ogun ọ̀run ń tẹ̀lé e, wọ́n gun ẹṣin funfun. Aṣọ tí wọ́n wọ̀ funfun, ó sì mọ́. Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare. A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.”
Ifi 19:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé: “Haleluya! Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá àti agbára, nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì, tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ̀ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.” Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé: “Haleluya! Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.” Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé: “Àmín, Haleluya!” Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé: “Ẹ máa yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti èwe àti àgbà!” Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé: “Haleluya! Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba. Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi, kí a sì fi ògo fún un. Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé, aya rẹ̀ sì ti múra tán. Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.” (Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.) Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.” Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.” Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ: ọba àwọn ọba àti olúwa àwọn olúwa.